Ìnáwó

(Àtúnjúwe láti Finance)

Sé Yorùbá bọ̀ wọ́n ní “Se bó o ti mọ ẹlẹ́wàà sàpọ́n. Ìwọ̀n eku nìwọ̀n ìtẹ́.” Wọn a sì tún máa pa á lówe pé “ìmọ̀ ìwọ̀n ara ẹni ni ìlékè ọgbọ́n nítorí pé ohun ọwọ́ mi ò tó ma fi gọ̀gọ̀ fà á, í í já lu olúwarẹ̀ mọ́lẹ̀ ni” áyé òde òní, àwọn ọ̀dọ́ tilẹ̀ máa ń dáṣà báyìí pé “dẹ̀ẹ́dẹ̀ẹ́ rẹ, ìgbéraga ni ìgbérasán lẹ̀.” Wọ́n máa ń sọ èyí fún ẹni tí ó bá ń kọjá ààyè rẹ̀ ni. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ ọgbọ́n kan se wí pé “ni àtètékọ́ṣe ni ọ̀rọ̀ wà,” bẹ́ẹ̀ náà ni ètò ti wà fún ohun gbogbo láti ìpilẹ̀sẹ̀ wá. Ètò ní í mú kóhun gbogbo rí rẹ́mú. Ọlọrun ọ̀gá ògo to da ayé. Ó fi ẹranko sígbó {àwọn olóró}. Ó tún fi ẹja síbú. Ó fi àwọn ẹyẹ kan sígbó. Ó fi àwọn mìíràn sílé. Àdìmúlà bàbá tó ju bàbá lọ tún fi ààlà sáààrin ilẹ̀, omi òkun, àti sánmọ̀. Ohun gbogbo ń lọ ní mẹ̀lọ̀-mẹ̀lọ. Bàbá dá àwa ọmọnìyàn kò fi ojú wa sí ìpàkọ́. Kò fi ẹsẹ̀ wa sórí kí orí wá wà lẹ́sẹ̀. Elétò lỌlọ́run gan-an.

Kíni ètò? Ètò jẹ̣́ ọ̀nà tí à ń gbà láti sàgbékalẹ̀ ohun kan tàbí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan lójúnà àti mú kí ó se é wò tàbí kó se é rí tàbí kó dùn ún gbọ́ sétí. A sẹ̀dá orúkọ yìí gan-an ni. Ohun tí a tò ní í jẹ́ ètò. Ẹ̀wẹ̀, ìnáwó ni ọ̀nà tàbí ìwà wa lórí bí a se ń náwó. Ohun pàtàkì ni láti sètòo bí a óò se máa ná àwọn owó tó bá wọlé fún wa. Ní àkọ́kọ́ ná, èyí yóò jẹ́ kí á mọ ìsirò oye owó tó ń wọlé fún wa yálà lọ́sẹ̀ ni o tàbí lósù, bí ó sì se lọ́dún gan-an ni. Bákan náà, yóò tún mú kó rọrùn fún wa láti mọ àwọn ọ̀nà tí owó náà ń bá lọ. Síwájú síi, ètò yóò ràn wá lọ́wọ́ láti le ní ìkọ́ra-ẹni-níjàánu lórí bí a se ń náwó wa. Bí a bá ti mú ìsàkọ̀tún tán, tí a tún mú ìsàkòsì náà, ìsàkusà ni yóò kù nilẹ̀. Tí a bá yọ ti ètò kúrò nínú ojúse ìjọba pàápàá sí ará ìlú, eré ọmọdé ni ìyókù yóò jẹ́. Gbogbo àwọn ẹka ìjọba pátá-porongodo ló máa ń ní àgbẹ́kalẹ̀ ìlànà tí wọn yóò tẹ̀lé lati mọ oye owó ti wọn n reti ati eyi ti wọn óò na bóyá fún odidi ọdún kan ni o tàbí fún osù díẹ̀. Èyí ni wọ́n ǹ pé ní ‘ÈTÒ ÌSÚNÁ’ Ìdí nìyí tó fi se pàtàkì fún gbogbo tolórí-tẹlẹ́mù, tòǹga-tòǹbẹ̀rẹ̀ ki kúlukú ní ètò kan gbòógì lọ́nà bí yóò se máa náwó rẹ̀. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní, “eku tó bá ti ní òpó nílẹ̀, kì í si aré sá. Bí a bá ti se àlàkalẹ̀ bí a óò se náwo wa yóò dín ìnákùùná kù láwùjọ wa. Ìnáwó àbàadì pàápàá yóò sì máa gbẹ́nú ìgbẹ́ wo wá láwùjọ wa. Mo ti sọ lẹ́ẹ̀ẹ̀kan nípa àwọn ẹka ìjọba mẹ́tẹ̀ẹ̀tà orílẹ̀ èdè yìí tí wọ́n máa ń sètò ìnáwó wọn. Àwọn wo ló tún yẹ kó máa sètò ìnáwó? Àwọn náà ni àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn oníṣòwò, àwọn ọmọ ilé-ìwé, níbi àsẹyẹ. Àwọn òsìsẹ́ ìjọba gbọdọ̀ sètò ìnáwó wọn kó sì gún régé. Ìdí ni pé, èyí ni yóò jẹ́ kí owó osù wọn tó í ná. Ẹni tó ń gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà lósù tí kò sì fi òdiwọ̀n sí ìnáwó rẹ̀ nípa títò wọ́n lésẹẹsẹ le máa rówó sohun tó yẹ láàákò tó yẹ nígbà tí ó bá ti náwó rẹ̀ sí àwọn ohun mìíràn tó seése kó nítumọ̀ ṣùgbọ́n tí kì í se fún àkókò náà.

Irú wọn á wá má ráhàn owó tósù bá ti dá sí méjì tàbí kí wọ́n jẹ gbèsè de owó osù mìíràn. Síwájú sí i, àwọn oníṣòwò gbọ́dọ̀ máa sètò to jíire lórí ìnáwó wọn. Nípa ṣíṣe èyí, wọn óò ni àǹfààní láti mọ̀ bọ́yá Ọláńrewájú ni iṣẹ́ wọn tàbí Ọláńrẹ̀yìn. Níbi tí àtúnṣe bá sì ti pọn dandan, “a kì í fòdù ọ̀yà sùn ká tó í nà án ládàá,” wọn kò nì í bèsù bẹ̀gbà, wọn óò sì se àtúnṣe ní wéréwéré. Àwọn ọmọ ilé-ìwé gan-an gbọdọ̀ mọ̀ pé ká sètò ìnáwó ẹni kì í sohun tó burúkú bí ti í wù kó mọ. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé ẹ̀kó gíga, béèyàn bá gbowó fún àwọn orísirísi ìnáwó láti ilé lórí ẹ̀kọ́ ẹni, ó seése kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ná ìná-àpà tó bá dé ààrin àwọn ẹlẹgbẹ́ẹ rẹ̀. Irú wọn ló máa ń pe ọ̀sẹ̀ tí wọ́n bá ti ilé lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn dé ní ‘Ọṣẹ ìgbéraga’ Èyí kò yẹ ọmọlúàbí pàápàá. Ó sì ń pè fún àtúnṣe. Ṣíṣe ètò tó gúnmọ́ lórí ọ̀nà tí à ń gbà náwó kò pin sí àwọn ọ̀nà tí mo sàlàyé rẹ̀ sókè yìí. Mo fẹ́ kó ye wá pé a le sètò ìnáwó wa níbi àwọn orísisi ayẹyẹ bí ìsọmọlórúkọ [tàbí ìkọ́mọ́jáde], ìgbéyàwó, oyè jíjẹ, ìṣílé, àti ìsìnkú àgbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi bí a se tó hàn wá ká le mọ ohun tí a óò dágbá lé níbi irúfẹ́ àṣeyẹ tí a bá fẹ́ í ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀ a ò ní í sí nínú àwọn tó máa ń pa òwe tó máa ń mú kí wọn kábàámọ̀ nígbẹ̀yìn ọ̀rọ̀. Òwe wọn ni, “rán aṣọ rẹ bí o bá se ga mọ.” Èyí tí wọn ì bá fi wí pé “rán aṣọ rẹ bí o bá se lówóo rẹ̀ sí.” Bí ẹni tó ga bá rán aṣọ rẹ̀ ní ‘bóńfò’ bó se lówó mọ ni, kò sì fẹ́ í sàsejù. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ le ti mọ̀ pé alásejù pẹ́rẹ́ ní í tẹ́. Bí a bá wá fẹ́ láti sètò ìnáwó wa, ó yẹ ká mọ̀ pé ìtòṣẹ̀ ló lỌ̀yọ̀ọ́, Oníbodè lo làààfin, ẹnìkan kì í fi kẹ̀kẹ́ síwájú ẹsin. Iwájú lojúgun í gbé. Ìnáwó tó bá ṣe kókó jùlọ tó sì ń bèèrè fún ìdásí ní kíákíá ló yẹ ká fi síwájú bí a se ń tò ó ní ẹsẹẹsẹ. Bí a bá wá kíyèsí pé ètò tí a là sílẹ̀ ti ju agbára wa lọ, ẹ jẹ́ ká fura nítorí pé akéwì kan wí pé:

“Ẹ fura óò!

Ẹ fura óò!

Páńsá ò fura

Páńsá jááná

Àjà ò fura

Àjá jìn

Ońlè tí ò bá fura

Olè ní ó ko o…”