Flora Gomes
Flora Gomes jẹ́ olùdarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè Guinea-Bissau. Wọ́n bi ní ìlú Cadique, orílẹ̀-èdè Guinea-Bissau ní Ọjọ́ 31 Oṣù kejìlá Ọdún 1949.[1] Ó lọ ilé-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Kúbà, ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ fíìmù ṣíṣe ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Instituto Cubano del Arte y la Industria Cinematográficos, èyí tí ó wà ní ìlú Havana.
Eré rẹ̀ kan tí ó ṣe ní ọdún 1988 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Mortu Nega[2] ni àkọ́kọ́ fíìmù àròṣe àti ẹ̀kejì fíìmù gígùn lórílẹ̀-èdè Guinea-Bissau. Fíìmù náà gba àmì-ẹ̀yẹ Oumarou Ganda Prize níbi ayẹyẹ FESPACO ti ọdun1989.
Ní ọdún 1992, Gomes darí eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Udju Azul di Yonta,[3] èyítí ó jẹ́ wíwò níbi ayẹyẹ Cannes Film Festival ti ọdún 1992.[4]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Flora Gomes at IMDB
- ↑ Mortu Nega at California Newsreel
- ↑ Udju Azul di Yonta at California Newsreel
- ↑ "Festival de Cannes: Udju Azul di Yonta". festival-cannes.com. Retrieved 2009-08-16.