Florence Banku Obi

Onkọ̀wé
(Àtúnjúwe láti Florence Obi banku)

Florence Banku Obi jẹ́ òṣìṣẹ́ akadá ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òǹkọ̀wé àti ọ̀jọ̀gbọ́n ti ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó yàtọ̀. Ó jẹ́ gíwá kọkànlá ti Fásitì Calabar àti gíwá-obìnrin àkọ́kọ́ láti ìgbà tí wọ́n tí dá ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti yàn án gẹ́gẹ́ bí adarí tuntun, ní Sẹ́nítọ̀ Ovie Omo-Agege tí ó jẹ́ alága ìgbìmọ̀ tó ń ṣáyẹ̀wò lórí ìwé òfin, ṣàpèjúwe ọ̀jọ̀gbọ́n Obi gẹ́gẹ́ bí "àwòkọ́ṣe ètò-ẹ̀kọ́ tó yanrantí.” Ó jẹ́ igbá-kejì gíwá tẹ́lẹ̀ rí, fún àwọn iṣẹ́ akadá àti kọmísánnà fún àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin ní Ìpínlẹ̀ Cross River. Ó jáde fún ipò gíwá ní ọdún 2015 ṣùgbọ́n kò wọlé títí di ọdún 2020 tí ó di obìnrin àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ jẹ. Ní ọdún 2007, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí amáwùjọ gbèrú àti ọmọ-ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ aṣòfin, Ìpínlẹ̀ Cross River.

Florence Banku Obi