Fola Evans-Akingbola

(Àtúnjúwe láti Fola-Evans Akingbola)

Fola Evans-Akingbola ( /ˈɑːknˈblɑː/) (tí a bí ní ọjọ́ ẹ̀rìn-dín-lọ́gọ́ta ọdún 1994)[3] jẹ́ òṣèré aláwọ̀ funfun ti British. Ó ṣe Maddie Bishop ní Freeform series, Siren. [4]

Fola Evans-Akingbola
Ọjọ́ìbíIyafolarinwa Oluseyi Rose Evans-Akingbola[1]
26 Oṣù Kẹ̀sán 1994 (1994-09-26) (ọmọ ọdún 30)
London, England, UK
Orúkọ mírànFola Akingbola
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́2014–present
AgentWilliam Morris Endeavor
Luber Roklin Entertainment
Identity Agency Group (IAG)[2]
Àwọn olùbátanJimmy Akingbola (uncle)

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀

àtúnṣe

Ní ìlú London ni wọ́n bí Evans-Akingbola sí ìyá onímọ̀-ìjìnlẹ̀ ará ìlú Gẹ̀ẹ́sì kan, Dókítà Gillian Evans, àti bàbá rẹ̀ akọrin ilẹ̀ Nàìjíríà Sola Akingbola (ti ẹgbẹ́ Jamiroquai). Ó dàgbà ní Bermondsey pẹ̀lú ègbọ́n rẹ̀ arábìnrin rẹ̀ nígbà tí ó sì ǹ kọ́ ẹ̀kọ́ ní Dulwich. Ó gba ẹ̀kọ́ eré ṣíṣe ní National Youth Theatre àti ní Identity School of Acting.[5]

Iṣẹ́ Rẹ̀

àtúnṣe

Ṣáájú kí ó tó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n, Evans-Akingbola ṣiṣẹ́ bí mọ́dẹ̀ẹ̀lì. Àwọn ìdánimọ̀ iṣẹ́ eré àkọ́kọ́ rẹ̀ jẹ́ fún BBC series Youngers and Holby City. Nígbà tí ó ń farahàn lórí jara kẹta ti BBC, Death in Paradise, Evans-Akingbola ni a sọ sínú jara olókìkí HBO Game of Thrones gẹ́gẹ́ bí ìyàwó kejì (tí wọ́n kò sọ lórúkọ) ti Khal Moro l'ákòókò jara kẹfà. Fún Netflix's Black Mirror (ìtẹ̀síwájú jara kẹrin tí ó ṣe àríyànjiyàn ní ọdún 2011), ó farahàn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ jara 2019 kan tí a pè ní “Striking Vipers" bí Mariella, arábìnrin tí ó jẹ́ ọdọ́ tó ń fẹ́ Karl (Yahya Abdul-Mateen II), ẹni tí ó jẹ́ ẹgbẹ́ olú-ẹ̀dá-ìtàn ti apá eré náà. Láti ọdún 2018, ó ti jẹ́ ẹ̀dá-ìtàn àkọ́kọ́ lórí Siren, tí ń ṣeré onímọ̀-ìjìnlẹ̀ omi òkun, Madelyn Bishop. Ó tún tí ṣe ìtọ́sọ́nà, ṣájọpọ̀ kíkọ ìtàn, ó sì ṣe àgbéjáde fíìmù kúkúrú kan tí a pè ní Grandma's 80th Surprise àti pé ó ṣe iṣẹ́ ohùn tí ó borí fún àwọn eré fídíò Assassin's Creed.


Àwọn Ìtọ́ka Sí

àtúnṣe
  1. "England and Wales Birth Registration Index, 1837-2008". Familysearch.org. 
  2. Petski, Denise (6 October 2016). "'The Deep': Alex Roe & Fola Evans-Akingbola Round Out Cast Of Freeform Pilot". Deadline.com. Penske Business Media, LLC. 
  3. "Fola Evans-Akingbola Wiki: Facts about the Star on Freeform's "Siren"". 18 March 2019. 
  4. Stockly, Ed (29 April 2020). "What's on TV Thursday: Last Man Standing on Fox; Coronavirus". Los Angeles Times. https://www.latimes.com/entertainment-arts/story/2020-04-29/whats-on-tv-thursday-april-30. 
  5. "Alumni". Identity School of Acting. 28 September 2019.