Folakemi Titilayo Odedina


Folakemi Titilayo Odedina(èni tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkànlélógún, osù kín-ín-ní, ọdún 1965), jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti olùkọ́ àgbà ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti ilẹ̀ Florida(University of Florida). Ó jẹ́ gbòógì atọpinpin fún "the Prostate Cancer Translantic Consortium(CaPTC)."[1] Ó tún jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ "America Cancer Society's National Prostate Cancer Disparities Advisory Team."[2]

Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀.

àtúnṣe

Folakemi, ní 1986, kẹ́kọ̀ọ́ jáde gboyè ìmọ̀ ìsègùn òyìnbó, èyiun "Pharmacy" ní fásitì ti Obafemi Awolowo(OAU), èyí tí ó fìgbàkanrí jẹ́ "University of Ife". Ní ọdún 1990, ẹ̀wẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ síwájú sí i láti lọ fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ lórí i ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òyìnbó kan náà ni fásitì ti 'Florida', èyiun "University of Florida". Ó parí èyí ní ọdún 1994. Àkọ́lé iṣẹ́-ìwádìí kíkọ lórí àbájáde ẹ̀kọ́ èyiun 'Ph.D. thesis' ti Folakemi kọ ni "Implementation of Pharmaceutical Care in Community Practice: Development of a Theoretical Framework for Implementation". Lẹ́yìn àbájáde ẹ̀kọ́ gíga 'Ph.D.' rẹ̀, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi olùrànlọ́wọ́ fún olùkọ́ àgbà ní fásitì ti West Virginia (West Virginia University).

Ìgbé ayé rẹ̀.

àtúnṣe

A bí Folakemi Titilayo Odedina sí inú ìdílé Ezekiel Shotayo Badejogbin àti Grace Modupe Badejogbin sí ìlú Abéòkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn, Nàìjíríà, èyiun lọ́jọ́ kọkànlélógún osù kín-ín-ní, ọdún 1965. Ní ìgbà èwe rẹ̀, ó gbé ní ìlú Èkó, ó sì lọ sílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ti girama "Apostolic Church Primary School" àti "Methodist Girls High School, Lagos", ní síṣẹ̀-n-tẹ̀lé.

Àmì-ẹ̀yẹ àti Ìdánimọ̀

àtúnṣe

Folakemi Titilayo Odedina ti gba àmì-ẹ̀yẹ̀ onírúurú fún ìdájọsí rẹ̀ sí sáyẹ́ǹsì àti ètò-ìlera. Ní ọdún 2009, ọ̀kan lára àmì-ẹ̀yẹ tí ẹgbẹ́ ẹ "American Society of Health Systems Pharmacy" àti "Association of Black Health-Systems Pharmacists" fi dá a lọ́lá ni "Leadership Award for Health Disparities". Àwọn mìíràn tún ni "Inspiring Women in STEM Award 2016" láti ọwọ́ ọ "INSIGHT Into Diversity", "Living Legend Award" láti ọwọ́ ọ" Clinical Trial Summit" ní ọdún 2017; ẹ̀wẹ̀, àmì-ẹ̀yẹ "William Award for Innovation in Cancer Care", láti ọwọ́ ọ" African Organization for Research and Training in Cancer" ní ọdún 2017.


Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Institute, National Cancer. "Prostate Cancer Transatlantic Consortium (CaPTC) | EGRP/DCCPS/NCI/NIH". epi.grants.cancer.gov. National Cancer Institute. Retrieved 2 February 2021. 
  2. College of Pharmacy, University of Florida. "Dr. Folakemi Odedina appointed to American Cancer Society and Nigerian University System research groups » College of Pharmacy » University of Florida" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). University of Florida Health Science Center. Retrieved 2 February 2021.