Folashade Abigeal Abugan (tí wọ́n bí ní 17 December 1990) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó jẹ́ eléré-ìárayá tó ń sáré irinwo (400) mítà. Òun ló gba àmì-ẹ̀yẹ onídẹ fún ìdíje irinwo míta ní 2007 All-Africa Games, tó sì tún wa padà gba àmì-ẹ̀yẹ onífàdákà nínú ìdíje 2008 African Championships, níbi tí ó ti fi àkọsílẹ̀ tuntun kalẹ̀, tó sáré fún ìṣẹ́jú àáyá 50.89. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ oníwúrà nínú ìdíje 2008 World Junior Championships in Athletics àti 2009 African Junior Athletics Championships.

Folashade Abugan
Òrọ̀ ẹni
Orúkọ kíkúnrẹ́rẹ́Folashade Abigeal Abugan
Ọmọorílẹ̀-èdèNàìjíríà Nàìjíríà
Ọjọ́ìbí17 Oṣù Kejìlá 1990 (1990-12-17) (ọmọ ọdún 34)
Sport
Erẹ́ìdárayáAthletics
Event(s)400 m
Updated on 27 August 2016.

Ó fara hàn nínú ìdíje ti ọdún 2010 Commonwealth Games ní ìlú Delhi, ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ onífàdákà fún Nàìjíríà nínú ìdíje irinwó (400) mítà àti mítà 4x400. Àmọ́ wọ́n já Abugan kúrò nínú ìdíje náà, tí wọn ò sì gbà á láyè láti kópa nínú ìdíje mọ́ nítorí wọ́n bá oògùn olóró nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò fun, tí wọ́n sì ri dájú pé ó ní testosterone prohormone, nínú èsì àyẹ̀wò náà.[1]

Àwọn àṣeyọrí rẹ̀

àtúnṣe
Jíjẹ́ aṣojú   Nàìjíríà
2006 Commonwealth Games Melbourne, Australia 2nd 4 × 400 m relay 3:31.83
World Junior Championships Beijing, China 8th 400 m 52.87
2nd 4 × 400 m relay 3:30.84 AJR
2007 rowspan=2 All-Africa Games Algiers, Algeria 3rd 400 m 51.44 PB
1st 4 × 400 m relay 3:29.74
2008 African Championships Addis Ababa, Ethiopia 2nd 400 m 50.89 PB
1st 4 × 400 m relay 3:30.07
World Junior Championships Bydgoszcz, Poland 1st 400 m 51.84
2009 African Junior Athletics Championships Bambous, Mauritius 1st 400 m 52.02 CR
DQ 4 × 400 m
2010 Commonwealth Games New Delhi, India DQ 400 m
DQ 4 × 400 m

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Commonwealth Games 2010: Third Nigerian tests positive. BBC Sport (2010-10-15). Retrieved on 2010-11-27.