Fortune Makaringe (ti a bi ni ọjọ ketala osu karun ọdun 1993) jẹ agbabọọlu afẹsẹgba alamọdaju ti orilẹ-ede South Africa ti o ngba aarin fun ẹgbẹ agbabọọluSouth Africa Premier Division Orlando Pirates . O tun gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu orilẹ-ede South Africa . Oun gba bọọlu tẹlẹ fun Maritzburg United .

Ti a bi ni Johannesburg, Makaringe bẹrẹ iṣẹ rẹ ni Moroka Swallows ṣaaju ki o to darapọ mọ Maritzburg United . Makaringe fowo si iwe adehun fun Orlando Pirates ni igba ooru 2019.

Makaringe gba bọọlu akọkọ rẹ fun South Africa ni ọjọ keta oṣu Okudu odun 2018 ni 0-0 ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Madagascar, botilẹjẹpe South Africa tẹsiwaju lati padanu ifẹsẹwọnsẹ 4-3 lori awọn ijiya. O jẹ ikan l'ara ẹgbẹ agbabọọlu mejidinlọgbọn akọkọ ti South Africa fun idije ife ẹyẹ ilẹ Afirika 2019 ṣugbọn ko jẹ ara àwọn ti ẹgbẹ agbabọọlu 23 ikẹhin wọn. [1]

Awọn itọkasi

àtúnṣe