Françoise Ellong (tí a bí ní 8 Oṣù Kínní, Ọdún 1988) jẹ́ olùdarí fíìmù àti ònkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù.

Françoise Ellong
Ọjọ́ìbí8 Oṣù Kejì 1988 (1988-02-08) (ọmọ ọdún 36)
Douala
Orílẹ̀-èdèCameroonian
Iṣẹ́Film director, writer
Notable workW.A.K.A. (2013)

Ìsẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

A bí Ellong ní ìlú Douala, orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù ní ọdún 1988. Nígbà tó wà lọ́mọdún mọ́kànlá, ó gbé pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan ní ìlú Brunoy, níbi tí ó ti kọ àkọ́kọ́ ìtàn rẹ̀. Ellong ḱopa nínu ìdíje kan tó wà fún àwọn ònkọ̀wé elédè Faransé ní ọdún 2002. Nípasẹ̀ ìdíje náà, ó padà wá ní ìfẹ́ sí kíkọ ìtàn eré.[1]

Ní ọdún 2006, àkọ́kọ́ fíìmú oníṣókí rẹ̀ táa mọ àkọ́lé rẹ̀ ní Les Colocs, jẹ́ gbígbéjáde. Ellong darí àkọ́kọ́ fíìmù gúngùn rẹ̀ ní ọdún 2013, èyítí àkọ́lé rẹ̀ jé W.A.K.A. Séraphin Kakouang ló ṣètò kíkọ eré náà, ṣùgbọ́n Ellong fúnrar̀ẹ ló dábàá ìtàn eré náà. W.A.K.A gba àmì-ẹ̀yẹ níbi ayẹyẹ <i>Festival du Cinéma Africain de Khouribga</i>, àti níbi ayẹyẹ Pan-African Festival of Cannes.[2] Ẹ̀kejì fíìmù gúngùn rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Buried jẹ́ gbígbéjáde ní ọdún 2020. Eré náà dá lóri pípàdé àwọn ọ̀rẹ́ àtijọ́ tí wọ́n ti pínyà fún ìgbà pípẹ́.[3] Ó rí ìwúrí láti ṣe fíìmù náà nínu ìròyìn kan tí ó rí lóri tẹlifíṣọ̀nù.[4]

Yàtọ̀ sí dídarí àti kíkọ ìtàn eré, Ellong tún ti ní àtẹ̀jáde ìwé tí àkọ́lé rẹ̀ n ṣe "Journal Intime d'Un Meurtrier," èyí tó jáde ní ọdún 2008.[5] Ní ọdún 2016, ó dá pẹpẹ ìròyìn kan sílẹ̀ tí ó pè ní "Le Film Camerounais", èyítí ó ṣokùn fa àwọn àmì-ẹ̀yẹ ti LFC.[4] Ellong pè fún yíyẹra fún Thierry Ntamack ní ọdún 2020, lẹ́hìn tí Ntamack sọ pé ìdá mẹ́wàá àwọn òṣèré Kamẹrúùnù ló mọṣẹ́ ṣe.[6]

Àkójọ àwọn ere rẹ̀

àtúnṣe
  • 2006: Les Colocs (short film, writer/director)
  • 2007: Dade (short film, writer/director)
  • 2008: Miseria (short film, writer/director)
  • 2009: Big woman don't cry (short film, writer/director)
  • 2010: Nek (short film, writer/director)
  • 2011: At Close Range (short film, writer/director)
  • 2011: When Soukhina disappeared (short film, writer/director)
  • 2012: Now and them (short film, writer/director)
  • 2013: W.A.K.A (director)
  • 2017: Ashia (short film, writer/director)
  • 2020: Buried (writer/director)

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe