Frank Donga
Kúńlé Ìdòwú, tí orúko ìnagije rẹ̀ jẹ́ Frank Donga, jẹ́ òṣèré àti apanilẹ́rìn-ín orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó di gbajúmọ̀ nígbà tí ó ṣe eré kan lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, The Interview, ní Ndani TV. Eré yìí jẹ́ eré apanilẹ́rìn-ín tó dá lórí awáṣẹ́ aláìbìkítà kan. Nípasẹ̀ yìí, wọ́n yán-án láti jẹ́ òṣèré apanilẹ́rìn-ín tó dára jù ní Africa Magic Viewers Choice Award ní ọdún 2015.[1] Ó ti kópa nínú àwọn eré àgbéléwò mìíràn bi The Wedding Party àti apá kejì rẹ̀The Wedding Party 2.[2] Ó ti fi ìgbà kan jẹ́ akọ̀ròyìn [3] tí ó sì ǹ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ayàwòran.[4]
Kunle Idowu | |
---|---|
Frank Donga at the 2018 Lagos Digital Summit | |
Ọjọ́ìbí | October 13 |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 2013-present |
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Nominees Announced for 2015 AMVCAs". Africa Magic Official Website - Nominees Announced for 2015 AMVCAs. Retrieved 2018-03-30.
- ↑ Adetiba, Kemi (2017-05-20), The Wedding Party, Alibaba Akporobome, Zainab Balogun, Daniella Down, retrieved 2018-03-30
- ↑ "'How I Use Comedy For Journalism' – Frank Donga". INFORMATION NIGERIA. 2017-08-05. http://www.informationng.com/2017/08/use-comedy-journalism-frank-donga.html.
- ↑ "KUNLE IDOWU 'FRANK DONGA' : FRANKLY SPEAKING ABOUT WORK AND LIFE". www.asikobeampeh.com. Retrieved 2018-03-30.