Fred Nuamah
Fred Nuamah (tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Frederick Kwaku Nuamah; tí wọ́n bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kọkànlá ọdún, 1975)[1] jẹ́ òṣèrẹ́kùnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Ghana, olùdarí eré àti aṣàgbéjáde fíìmù. Ó gbajúmọ̀ fún fíìmù The Game. Òun ni olùdásílè Ghana Movie Awards àti Ghana TV series Awards, èyí tó jẹ́ ayẹyẹ ọdọọdún láti fi bu ọlá fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ takuntakun nínú ẹ̀ka eré-ìdárayá ilè Ghana.[2][3][4][5]
Fred Nuamah | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Frederick Kwaku Nuamah 5 Oṣù Kọkànlá 1975 Accra, Ghana |
Orílẹ̀-èdè | Ghanaian |
Iṣẹ́ | |
Gbajúmọ̀ fún | The Game, Pool Party, Amakye and Dede |
Àwọn ọmọ | 1 |
Ayé àti iṣẹ́ wọn
àtúnṣeWọ́n bí Nuamah sí ìlú Accra, ìlú Ada àti Obuasi, ló sì ti wá, èyí tí ó wà ní Ashanti Region ní apá ilẹ̀ Gúúsù ilẹ̀ Ghana.
Ó di gbajúmọ̀ lẹ́yìn tó kópa nínú fíìmù Matters of the Heart ní ọdún 1993. Ó tẹ̀síwájú láti kópa nínú àwọn fíìmù bíi The Prince Bride, Heart of Men, Material Girl and 4 Play. Ní ọdún 2010, Nuamah farahàn nínú The Game, èyí tí Abdul Salam Mumuni darí.[6] Nuamah ṣe ẹ̀dá-ìtàn kan nínú Amakye and Dede, èyí tí ìṣàfihàn àkọ́kọ́ rẹ̀ wáyé ní Silverbird Cinemas in Accra on March 26, 2016.[7] Nuamah kópa nínú fíìmù Amakye and Dede tí ìṣàfihàn àkọ́kọ́ rẹ̀ wáyé ní Silverbird Cinemas ní Accra ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, ọdún 2016.[8] Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ National Democratic Congress, Ó sì díje dupò òṣèlú kan (NDC[9]) fún Ayawaso West-Wuogon,[10] àmọ́ ó padà jáwọ́ láti gba John Dumelo láàyè[11] láti gun orí oyè náà.[12]
Ghana Movie Awards
àtúnṣeNí ọjọ́ kìíní oṣù kìíní ọdún 2009, Nuamah ṣe ìdásílẹ̀ Ghana Movie Awards, níbi tí ó ti di ipò adarí àgbà mú.[13]
Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀
àtúnṣe- Matters of the Heart, 1993 (Cameo Role)
- The Prince Bride (Supporting Role) 2009
- The Heart of Men (Supporting Role) 2009
- The Game, 2010[14]
- Material Girl (Supporting Role) 2010
- 4 Play (Supporting Role) 2010
- Temptation (Supporting Role) 2010
- 4 Play Reloaded (Supporting Role) 2011
- Pool Party (Supporting Role) 2011[15]
- Amakye and Dede, 2016[16][17]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ November 5, Fred Nuamah Full Name Frederick Kwaku Nuamah Born; Awards, 1975Nationality Ghanaian Occupation Actor Relationship Status Single Awards Not Available Organization Ghana Movie. "Fred Nuamah Biography: Age, Awards, Wiki, Trends, Net Worth, Actor" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-24.
- ↑ "Ghanaian Actor Fred Nuamah Gifts Wife a Porsche". Bella Naija. 1 August 2018. https://www.bellanaija.com/2018/08/ghanaian-actor-fred-nuamah-gifts-wife-porsche/. Retrieved 29 October 2019.
- ↑ "Ghana Movie Awards Boss Graces Cannes’ Red Carpet!". News Ghana. 23 May 2012. https://www.newsghana.com.gh/ghana-movie-awards-boss-graces-cannes-red-carpet/. Retrieved 29 October 2019.
- ↑ "Fred Nuamah’s “Pajamas” & Van Vicker’s strange rosary on Fashion 101". Today GH. 10 February 2012. Archived from the original on 29 October 2019. https://web.archive.org/web/20191029180535/https://www.todaygh.com/fred-nuamahs-pajamas-van-vickers-strange-rosary-on-fashion-101/. Retrieved 29 October 2019.
- ↑ "Things must change with the Ghana Movie Awards". Graphic.com.gh. 8 December 2016. https://www.graphic.com.gh/features/things-must-change-with-the-ghana-movie-awards.html. Retrieved 29 October 2019.
- ↑ "The Body Of A Woman Itself Is A Temple of Evil. In this Temple I Will Gladly Worship. The Game, A Must Watch Movie…..". Ghana Celebrities. 12 June 2010. https://www.ghanacelebrities.com/2010/06/12/the-body-of-a-woman-itself-is-a-temple-of-evil-in-this-temple-i-will-surely-worship-says-majid-michel-the-game-a-must-watch-movie/. Retrieved 29 October 2019.
- ↑ "Movie Review: Amakye and Dede". Ghana Film Industry. Archived from the original on 2 April 2019. https://web.archive.org/web/20190402114341/http://www.ghanafilmindustry.com/amakye-and-dede-movie-review/. Retrieved 29 October 2019.
- ↑ "Movie Review: Amakye and Dede". Ghana Film Industry. Archived from the original on 2 April 2019. https://web.archive.org/web/20190402114341/http://www.ghanafilmindustry.com/amakye-and-dede-movie-review/. Retrieved 29 October 2019.
- ↑ "National Democratic Congress (Ghana)", Wikipedia (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì), 2023-06-15, retrieved 2023-08-09
- ↑ "Ayawaso West", Wikipedia (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì), 2022-04-14, retrieved 2023-08-09
- ↑ "John Dumelo", Wikipedia (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì), 2023-08-08, retrieved 2023-08-09
- ↑ "Fred Nuamah withdraws from NDC’s Ayawaso". Citinewsroom - Comprehensive News in Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2023-08-08. Retrieved 2023-08-09.
- ↑ "Ladies Now Testify About Me – Fred Nuamah". Daily guide network.. 20 September 2016. https://dailyguidenetwork.com/ladies-now-testify-about-me-fred-nuamah/. Retrieved 29 October 2019.
- ↑ "The Game, Full Cast & Crew". IMDb. https://www.imdb.com/title/tt1773736/fullcredits/?ref_=tt_ov_st_sm. Retrieved 29 October 2019.
- ↑ "Celebs Out & About: Photos From The Premiere Of ‘Pool Party’ Featuring Majid Michel & Mum + Jackie Appiah + Abdul Sallam Mumini + Yvonne Okoro + Fred Nuamah + Frank Raja Arase & TV3 Ghana’s Most Beautiful Nasara…". Ghana Celebrities. https://www.ghanacelebrities.com/2011/02/12/celebs-out-about-photos-from-the-premiere-of-pool-party-featuring-majid-michel-mum-jackie-appiah-abdul-sallam-mumini-yvonne-okoro-fred-nuamah-frank-raja-arase-tv3-gh/. Retrieved 29 October 2019.
- ↑ "Amakye and Dede Movie To Be Premiered in UCC and KNUST This Weekend". kuulpeeps. https://kuulpeeps.com/2016/04/amakye-and-dede-movie-to-be-premiered-in-ucc-and-knust-this-weekend/. Retrieved 29 October 2019.
- ↑ "Photos from the premiere of ‘Amakye & Dede’". ameyawdebrah. https://ameyawdebrah.com/photos-premiere-amakye-dede/. Retrieved 29 October 2019.