Frejon

Ẹ̀wà alágbọn

Frejon (Láti Feijão, tó jé ọ̀rọ̀ Portuguese fún ẹ̀wà) jẹ́ ẹ̀wà tí wọ́n sè pẹ̀lú omi àgbọn tí àwọn Kìrìsìtẹ́ẹ́nì (pàápàá jù lọ àwọn Kátólíìkì) máa ń jẹ lásìkò ọ̀sẹ̀ mímọ́ káàkiri àgbáyé. Àwọn ìlú tí Frejon ti gbajúmọ̀ jù lọ ni Brazil àti Nàìjíríà (pàápàá jù lọ láàárín àwọn ọmọ Yorùbá tó padà sí ilẹ̀ Nàìjíríà, sí agbègbè "Brazilian Quarters" ní Lagos Island láti ìlú Brazil léyìn tí wọ́n fi òǹtẹ̀ lu òwò ẹrú), àti ní Sierra Leone ní Good Friday, tàbí fún ayẹyẹ bí ìgbéyàwó.[1] Oúnjẹ yìí ni wọ́n máa ń jẹ ní good Friday lásìkò Easter nítorí kò sí oore-ọ̀fẹ́ láti jẹ àwọn oúnjẹ ẹlẹ́jẹ̀, ẹran, ẹja àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lásìkò yìí.

Wọ́n máa ń jẹ frejon ní Nàìjíríà àti ní apá Ìwọ̀-oòrùn ilè Africa, ó sì jẹ́ àsèpọ̀ ẹ̀wà dúdú tí wọ́n fi iná igi sè lórú mọ́jú tí wọ́n sì fi omi àgbọ́n sínú rẹ̀ kí ó ba lè dùn. Ní àwọn ìlú mìíràn, wọ́n máa ń fi kòkó sí inú rẹ̀.[1] Wọ́n máa ń fi ọbẹ̀ ata, ìgbín alátà àti gaàrí Ìjẹ̀bú jẹ Frejon.[2]

Ìyàtọ̀ mìíràn

àtúnṣe
  • Ata, edé, iyọ̀ àti tòmátò náà le wà nínú ẹwà náà tí wọ́n fi omi àgbọn sí.
  • Wọ́n le fi ṣúgà bákan náà sínú frejon. Tí wọ́n sì máa fi ṣe ohun mímú.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Webb, Lois Sinaiko (2000). Multicultural Cookbook of Life-Cycle Celebrations. Cookbooks for Students Series. ABC-CLIO. ISBN 1-57356-290-4. https://archive.org/details/multiculturalcoo00lois. 
  2. "Frejon aka Coconut and Beans". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-06-12. Retrieved 2022-03-15.