Fuat Sezgin (Láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù Ọ̀wàwà ọdún 1924, sí ọjọ́ Ọgbọ̀n oṣù Èbìbí ọdún 2018) jẹ́ ọ̀mọ̀wé àti olùṣèwádìí ilẹ̀ Turkish, èyí tí ó yan ṣíṣe àwárí ìtàn Sáyẹ́ǹsì ẹ̀sìn Ìsìlámù ti ilẹ̀ Lárúbáwá láàyò. Ọ̀jọ̀gbọ́n tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀rí ni, ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìtàn Sáyẹ́ǹsì ajẹmọ́ àdáyébá ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Johann Wolfgang Goethe ní ìlú Frankfurt ní orílẹ̀-èdè Jamaní. Bákan náà ló tún jẹ́ olùdásílẹ̀ àti olùdarí ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ ìtàn Sáyẹ́ǹsì Ìsìlámù ti àwọn Lárúbáwá ní ilé-ẹ̀kọ́ náà.[1] Ó tún ṣẹ̀dá Ilé-ọnà sí Frankfurt àti Istanbul èyí tó kó àwọn ohun irinṣẹ́ ajẹmọ́ ìtàn Sáyẹ́ǹsì Ìsìlámù ilẹ̀ Lárúbáwá, pẹ̀lú àwọn èròjà àti àwòrán ayé. [2] Àtẹ̀jáde rẹ̀ tó gbajúmọ̀ jùlọ ni àtẹ̀jáde ìkẹtàdínlógún, Geschichte des Arabischen Schrifttums,èyí tí ìtọ́kasí rẹ̀ tẹ̀wọ̀n jùlọ nínú iṣẹ́ rẹ̀.[3]

Fuat Sezgin
Ọjọ́ìbí(1924-10-24)24 Oṣù Kẹ̀wá 1924
Bitlis, Turkey
Aláìsí30 June 2018(2018-06-30) (ọmọ ọdún 93)
Istanbul, Turkey
Orílẹ̀-èdèTurkish
Iléẹ̀kọ́ gígaIstanbul University
Iṣẹ́Science historian academic
Olólùfẹ́Ursula Sezgin
AwardsKing Faisal International Prize
Order of Merit of the Federal Republic of Germany
Presidential Culture and Arts Grand Awards

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Sezgin gba oyè ìjìnlẹ̀ gíga láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Istanbul lábẹ́ ará ilẹ̀ Jamaní tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa èdè,ìtàn, àṣà ìlà-oòrùn, Hellmut Ritter ní ọdún 1950. Orúkọ ìwé ìwádìí àṣekágbá rẹ̀ ń jẹ́ "Buhari’nin Kaynakları" [4](Orísun Al-Bukhari)sọ pé ó fẹ́ lòdì sí ìgbàgbọ́ àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ èdè, ìtàn àti àṣà ará ilẹ̀ Íróòpù.Àtúnṣe Al-Bukhari jẹ́ àkójọpọ̀ hàdísì èyí tí orísun rẹ̀ wá láti sẹ́ńtúrì keje àti àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu.Ó gba ipò ní ilé-ẹ̀kọ́ Istanbul, ṣùgbọ́n èyí tí ó padà fi sílẹ̀ látàrí ọ̀tẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1960. Ó kó lọ sí ilẹ̀ Jamaní ní ọdún 1961,tí ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi Ọ̀jọ̀gbọ́n alábẹ̀wò ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Frankfurt. Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà ní ọdún 1965. Àfojúsùn iṣẹ́ ìwádìí rẹ̀ ní Frankfurt dálé àsìkò Ìdùnnú, Aṣeyọrí àti Ìlọsíwájú, Sáyẹ́ǹsì Ìsìlámù.Ní ọdún 1982, Sezgin dá ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ ìtàn Sáyẹ́ǹsì Ìsìlámù ilẹ̀ Lárúbáwá. Lónìí ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ náà ló ní àwọn ìwé tó kún jùlọ fún ìtàn Sáyẹ́ǹsì Ìsìlámù ti ilẹ̀ Lárúbáwá ní àgbáyé.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "UKM to confer honorary doctorate on Prof Fuat Sezgin". New Straits Times. 8 January 2007. 
  2. "Islam History of Science and Technology Needs to Speak". Turkish Daily News. 27 December 2008.  The utility of a museum of replicas in an antiquarian field contaminated by fakes is discussed by Prof. Nir Shafir at the Internet web site Aeon in 2018 at https://aeon.co/essays/why-fake-miniatures-depicting-islamic-science-are-everywhere
  3. Gerhard Endreß (26 October 2004). "Tradition und Aufbruch" (in German). Frankfurter Rundschau. http://de.qantara.de/wcsite.php?wc_c=3241. 
  4. "M.Fuad SEZGİN, Buhari'nin Kaynakları Hakkında Araştırmalar, Ankara Üniversitesi İlahiyat Fakültesi, ANKARA, 1956.". Archived from the original on 10 September 2012. Retrieved 31 July 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)