Fúnmiláyọ̀ Ransome-Kútì

(Àtúnjúwe láti Funmilayo Ransome-Kuti)

Oloye Funmilayo Ransome-Kuti, MON, ni a bí ni Frances Abigail Olufunmilayo Thomas; ni ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹwa ọdun1900 ó sì jade laye ni ọjọ́ kẹtala oṣu kẹrin ọdun1978); a tun mọ si Funmilayo Anikulapo-Kuti. Ó jẹ́ olukọni, oloṣelu, alagbọrandun ati a jà-f'ẹtọ awọn obinrin ni orilẹ-ede Naijiria.[1]

Funmilayo Ransome-Kuti
Funmilayo Ransome-Kuti graduate during her graduation
Ọjọ́ìbí25 October,1900
Abeokuta, Ogun State
Aláìsí13 April,1978
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́olukọni,oloṣelu, alagbọrandun,A jà-f'ẹtọ awọn obinrin ni orilẹ-ede Naijiria
Olólùfẹ́Israel Oludotun Ransome-Kuti
Àwọn ọmọ4

Ìlú Abeokuta, ni ipinlẹ Ogun ni orilẹ-ede Naijiria ni a ti bi Fumilayo Ransome Kuti, òun sì ni akẹkọ obinrin akọkọ ti o lọ si ile-iwe girama ti ilu Abeokuta[2]. Ní ìgbà tí Funmilayo Ransome Kuti wa ni ọ̀dọ́langba, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, oun ni o si kọ́kọ́ ṣe ètò ile ẹko ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni orilẹ-èdè Naijiria ti o si tun ṣe iranlọwọ eto ẹkọ àgbà fún àwọn obinrin ti eto ọrọ aje wọn ko gbe pẹẹli.

Ní ọdún diẹ sẹyin (1940), Ransome-Kuti dá Ẹgbẹ́ Iṣokan awọn ọmọbinrin Abẹokuta (Abeokuta Women's Union) silẹ,[3] ó sì ń jà fitafita fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin wipe ki awọn ijọba ibilẹ fi opin si owó orí ti kò tọna ti won n gba lọwọ awon iya'lọja. Funmilayo, ti awọn oniroyin ṣe apejuwe rẹ gege bi "Abo Kiniun ti Lisabi", [4] :77 ṣe agbatẹru iwọde ifẹhonu han awọn obinrin tó lé ni ọkẹ marun (ẹgbẹrun mẹwa) eleyi si mu ki Alake ilẹ Ẹgba tó wà lori oye ni akoko naa (ọdun 1949) fi ori oye silẹ. Bi Ransome-Kuti ṣe n gbajumọ si ni agbo oṣelu, o kopa ninu eto gbigba ominira fun orilẹ-ede Naijiria nipa didara pọ mó oriṣiriṣi idanilẹkọ ati awọn aṣoju ti o lọ si oke okun lati ṣe agbekale iwe ilana ati ofin isejọba orilẹ ede Naijiria. Funmilayọ ni o ṣe agbatẹru idasilẹ agbarijọpọ ẹgbẹ́ àwọn obinrin ní tìbú-tòòró orilẹ-ede Naijiria, o si ja fun ẹtọ àti dibo fun àwọn obinrin, ati wipe nipa eyi, o di ọkan pataki lara awọn to du alaafia ati ẹtọ awọn obinrin ni gbogbo orilẹ-ede agbaaye.

Oniruuru ami ẹ̀yẹ ni Ransome-Kuti gba, lara won ni Lenin Peace Prize a si tun daa lọla gegebi ọmọ ẹgbẹ Order of the Niger fun awon iṣẹ ribiribi to gbe ṣe. Ni irọlẹ aye Ransome-Kuti, o pa ohùn rẹ̀ pọ̀ mó ti ọmọ rẹ lati doju kọ ijọba ológun ni orilẹ-ede Naijiria. Ẹni ọdun mẹta-din-lọgọrin ni nigba ti o jade láyé ohun ti o si se okunfa iku rẹ ni ifarapa ti o ni nigbati awọn ọmọ ologun orilẹ-ede Naijiria fi ipá wọ inu ile rẹ. Lara awọn ọmọ Funmilayọ Ransome-Kuti ni gbaju-gbaja olorin juju ni Fela Kuti, dokita ati ajafẹtọ ọmọniyan, Beko Ransome-Kuti, ati minisita fun eto ilera ni orilẹ-ede Naijiria nigba kan ri, Ransome-Kuti.

Àwọn ìtókasí

àtúnṣe
  1. "Funmilayo Ransome-Kuti". Encyclopedia Britannica. 1900-10-25. Retrieved 2022-05-19. 
  2. https://www.aljazeera.com/features/2020/10/1/the-lioness-of-lisabi-who-ended-unfair-taxes-for-nigerian-women
  3. "Funmilayo Ransome-Kuti biography". Women. 1970-10-24. Retrieved 2022-05-19. 
  4. Johnson-Odim, Cheryl. For Women and the Nation: Funmilayo Ransome-Kuti of Nigeria. https://books.google.com/books?id=ZyMyspsywPsC.