Gígé igi lulẹ̀ ní Nàìjíríà
Gígé igi láti ṣe pákó, gígé igi lulẹ̀ láti gbin irúgbìn àti gígé igi lulẹ̀ láti fi dánọ́ jẹ́ gbòógì jùlọ nínú àwọn ìdí tí àwọn ènìyàn fi ń gé igi lulẹ̀ ní Nàìjíríà.[2][3]
Láàrín ọdún 2000 sí 2005,[4] Nàìjíríà jẹ́ rílẹ̀-èdè tí ó gé igi lulẹ̀ jùlọ ní àgbáyé,[5] gẹ́gẹ́ bí àjọ the Food and Agriculture Organization ti United Nations (FAO) ṣe sọ.
Ní àwọn ọdún 1950s, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ ni wọ́n fi òfin dè pé kí ẹnikẹ́ni má gégi níbẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n ti gé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn igi tí ó wà ní àwọn ilẹ̀ yìí lulẹ̀,[4] ọkàn lára àwọn ìdí tí eléyìí fi ṣẹlẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan ni àwọn ènìyàn ń ṣe lónìí tí ó nílò kí wọ́n lo igi.
Àwọn ìdí tí wọ́n fi ń gégi lulẹ̀
àtúnṣeỌ̀pọ̀lopọ̀ ǹkan ní òun fa gígé igi lulẹ̀ ní Nàìjíríà.
Iṣẹ́ àgbẹ̀
àtúnṣeIlẹ̀ tí àwọn àgbè nílò fún gbí gbin ǹkan ọ̀gbìn ń posi nítorí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń pò si lólojúmọ́, èyí mú kí àwọn àgbẹ̀ ma gé àwọn igi inú igbó lẹ̀ láti fi àwọn ilẹ̀ náà ṣe oko.[6] Àwọn àgbẹ̀ míràn tún féràn kí wọ́n ma gbin ọ̀gbìn sí àwọn ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọdọọdún
Wíwá epo
àtúnṣeWíwá epo ti fa kí wọ́n gé ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi lulẹ̀ ní Nàìjíríà.
Lílo igi dáná
àtúnṣeBí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé Nàìjíríà wà lára àwọn orílẹ̀ èdè tí ó ń ta epo. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Nàìjíríà sì ń lọ igi dáná, pàápàá jùlọ, àwọn tí ó ń dáná níbi ìnáwó, èyí mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ma gé igi lulẹ̀ láì gbin òmíràn.[6]
Ọ̀làjú
àtúnṣeNítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ń kó lọ àwọn ìlú ńlá, ó jẹ́ dandan fún àwọn inú igbó àwọn ìlú yìí láti gé àwọn igi inú igbó wọn kalẹ̀ láti kọ́ ojú ọ̀nà, ilé-ìwé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. railways, bridges, schools, in these parts of the country which are now threats to the forests areas as trees and vegetations are cut down or burnt to achieve these development plans.[6]
For instance, most first generation and second generation universities like University of Calabar were highly forested areas but the need to establish these schools made way for the destruction of these areas.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Fashae, Olutoyin (2017). "Geospatial Analysis of Changes in Vegetation Cover over Nigeria". Bulletin of Geography (13): 17–27. https://www.researchgate.net/publication/321953126.
- ↑ "Nigeria has worst deforestation rate, FAO revises figures". Mongabay Environmental News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2005-11-17. Retrieved 2022-02-26.
- ↑ "Deforestation in Sub-Saharan Africa". web.mit.edu. Retrieved 2022-02-27.
- ↑ 4.0 4.1 "Deforestation statistics for Nigeria". Mongabay. Retrieved 2021-04-09.
- ↑ "Challenges Facing Policies Against Deforestation in Nigeria". earth.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-01-18. Retrieved 2022-02-26.
- ↑ 6.0 6.1 6.2 "Deforestation in Nigeria: 7 Causes, 5 Effects and 6 Ways to Stop It". InfoGuideNigeria.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-11-07. Retrieved 2022-03-14.