Gúdúgúdú
Gúdúgúdú Ìlù yi gan an là bá máa pè ní omele dùndún. Igi la fi n gbẹ́ ẹ, ṣùgbọ́n ojù kansoso lo nì. O fi èyí yatọ si awọn bi ìyá-ìlù, kẹrikẹri, Gangan, ìsaájú ati kànnàngó ti wọn ni ojù méjìméjì.
Ìlù yìí kò se gbé kọ́ apá bi ti àwọn yòókù ọrùn la máa ń gbé e kọ́ nígbà tí a bá ń lùú. Bí o ti kéré tó ipa tí ó ń kó nínú ìlù dùndún kò kéré. Kerekere ní ń dún nígbà gbogbo nítorí pé awọ ojú ìlù náà kò dẹ̀ rárá.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |