Ọjọgbọn Gabriel Jimọh Afọlabi Ojo (Ọdún 1929-2020) jẹ olùkọ́ àti olùdarí ilé ìjọ Catholic tí orílẹ̀ Nàìjíríà . Wọn bí arákùnrin náà ni ọjọ àkọ́kọ́, oṣu November, ọdún 1929 ni Ado-Ekiti , ilẹ Naijiria níbi tó ti ṣe igbiyanju nínú ẹkọ àti ṣiṣẹ́ fún àgbègbè rẹ[1].

Ìgbésí Ayé àti Ẹ̀kọ́ Afọlabi

àtúnṣe

Afọlabi bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ ni ilẹ ìwé St. George's Catholic ni Ado-Ekiti níbi tó ti lọ ilé ìwé akọ bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1936 de 1942. Lẹyin naa lo lọsí collegi idanilekọ tí St. John Bosco (1944-1945) to sì gba iwe ẹri ilé ìwé cambridge ni oṣù December, ọdun 1948[2].

Gẹgẹbi ẹni tó fẹ́ràn àti keekọ, ó gba iwe ẹri gíga tí olukọ ni ọdún 1950 àti Matriculation tí London ni person oṣu June, ọdún 1951. Ní ọdún 1953, ọjọgbọn Ọjọ́ lọ sí ilé ìwé gíga tí Ireland láti keekọ sì níbi tó ti jáde gẹgẹ bí akeekọ tó pegede julọ Akọkọ kíláàsì ni ọdún 1956 tí oloyinbo mọ si "First Class". Arákùnrin náà jẹ ọmọ ilẹ̀ Afíríkà àkọ́kọ́ àti ṣe iru ẹ ní ipilẹ-ayé àti ọrọ ajé láti ilé ìwé rẹ. Lẹyin naa lo gba iwe ẹri ti Master pelu ipò tó ga julọ ni ọdun 1957 tó sì tún gbà Ph. D. ní ọdún 1963[3].

Ọjọgbọn Ojo bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ rẹ gẹgẹbi olùkọ́ ni Ado-Ekiti ni ọdun 1946. Lẹ́yìn náà lo di olùkọ́ ni Collegi St Joseph ni ipinlẹ Òndó. Ní ọjọ́ akọkọ, oṣù October, ọdún 1970, arákùnrin náà di ọjọgbọn lórí imọ Ìpínlẹ̀ ayé[4].

Ọjọgbọn Gabriel Jimọh Afọlabi fẹ́ arábìnrin Florence Bukunola Ojo (née Adeyanju), tí wọn sì bí ọmọkùnrin mẹta àti ọmọbìnrin mẹta. Arákùnrin náà kú ní ọjọ́ ọgbọn, oṣu August, ọdún 2020[5].

Ẹyẹ àti idanimọ

àtúnṣe

Ọjọgbọn Ọjọ́ gbajumọ nínú ẹkọ àti ibi iṣẹ rẹ. Afi jẹ ọmọ ẹgbẹ́ tí ìjọ Soviet Socialist Republics (USSR) to sì gba ami ẹyẹ gẹgẹ bi Mountaineer ni ipinlẹ West Virginia, USA. Ní ọdún 2004, Afi jẹ òye ọgagun Order tí Niger (CON) gẹgẹbi ìṣe takuntakun tó ṣe sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà[1].

Àwọn Itọkasi

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 "Renowned Academic, Afolabi Ojo, Passes on at 90 – THISDAYLIVE". THISDAYLIVE – Truth and Reason. 2020-09-01. Retrieved 2023-10-03. 
  2. "OJO, Prof. Gabriel Jimoh Afolabi". Biographical Legacy and Research Foundation. 2017-02-07. Retrieved 2023-10-03. 
  3. "Celebrating Accomplished Academic, Professor Ojo, at 90 – THISDAYLIVE". THISDAYLIVE – Truth and Reason. 2019-11-03. Retrieved 2023-10-03. 
  4. "Pro Afolabi Ojo Archives". Edugist - Leading Africa’s Education Conversation. 2020-09-04. Retrieved 2023-10-03. 
  5. "Governor Fayemi Mourns Renowned Educationist, Prof. Ojo’s Death – Ekiti State Website". Ekiti State Website – Official Website of the Government of Ekiti State. 2019-09-15. Retrieved 2023-10-03.