Gabriel Mojísọ́lá Babátúndé

Gabriel Mojísọ́lá Babátúndé ní wọ́ bí ní ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Kẹ́sààn, ọdún 1938 (September 14, 1938) ní ìlú Akinmorin, ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀Afijio Local Government Area of in Ìpínlẹ̀ Òndó Nigeria. Òun ni ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n àkọ́kọ́ fún ìmọ̀ Sáyẹ̀nsì nípa ẹranko (Professor of Animal Science) ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]

Gabriel Mojisola Babatunde
Ọjọ́ìbíOṣù Kẹ̀sán 14, 1938 (1938-09-14) (ọmọ ọdún 85)
Akinmorin, Afijio
Orílẹ̀-èdèNigerian

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Babátúndé lọ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní St. John School, ní Akinmorin láàrín ọdún 1944-1950, tí ó sì tún lọ sìílé ẹ̀kọ́ St. David School, nì ìlú Kúdetì ní Ibadan, láàrín ọ̀dún 1951-1952. Ó tẹ̀ síwájú nílé-ẹ̀kọ́ Government College tí ó wà ní ìlú Ìbàdàn láàrín ọdún 1952-1959.[2] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè àkọ́kọ́ ( B.Sc (hons) nínú ìmọ̀ ọ̀gbìn, tí ó sì jáde pẹ̀lú ipele Kejì (second class upper division) ní ìlú London, Ó gba oyè ìmọ̀ ẹlẹ́kejì ìyẹn (M.Sc), àti oyè ọ̀mọ̀wé (PhD) nínú ìmọ̀ (Animal Nutrition, Monogastrics) ní Fásitì Cornell , ní ìlú Ithaca, New York ní ọdún 1967. Bákan náà ni ó tún ní àwọn ìjànján ìwé ẹ̀rí (postgraduate and diplomas and qualification, as an IAEA trainee) lórí bí a ṣe ń lo (radioisotopes àti radiation) nínú ìmọ̀ Sáyẹ́nsì Ẹranko(Animal Science and Veterinary Medicine) láti ilé-ẹ̀kọ́ Belgrade, Yugoslavia ní ọdún 1970.[3]

Àjọ àti ìjọ̀mọ ẹgbẹ́ rẹ̀ àtúnṣe

Babátúndé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn American Registry of Professional Animal Scientists (ARPAS) láti ọdún 1974. Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Nigerian Society for Animal Production. Ẹ̀wẹ̀, ó tún jẹ́ American Society of Animal Science. Bákan náà ni ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àjọ Agricultural Society of Nigerian, tí ó sì túnnjẹ́ ọ̀kan lára àjọ Science Association of Nigeria and Nigerian Institute of Animal Science.[3]

Ìyànsípò rẹ̀ àtúnṣe

Ọ̀jọ̀gbọ́n Babàtúndé ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Olùkọ́ onípò kejì(Lecturer II) ní ẹ̀ka ètọ́ ẹ̀kọ́ Animal Science Department, Fásitì ìbàdàn láàrín ọdún 1967-1969. Wọ́n sọọ́ di olùkọ́ onípò kíní (Lecturer I) ní ẹ̀ka ètò kan náà, tí ó sì ṣiṣẹ́ nípò yí fún ọdún kan kí ó tún tó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n ní abala iètò ẹ̀kọ́ Animal Nutrition nínú ọgbà kan náà láàrín ọdún 1972-1977.[2] Wọ́n yàn án sípò Ọ̀jọ̀gbọ́n Animal Nutrition (Monogastrics) ní abala ètọò ẹ̀kọ́ Animal Science kan náà ní Fásitì Ìbàdàn fún sáà ètò-ẹ̀kọ́ 1976/77 . Òun náà tún ni Olóòtú àgbà fún àjọ oníwèé ìrọ́yìn nípa ìpèsè ẹranko (Animal Production) láàrín ọdún 1977-1980. Ẹ̀wẹ̀, ó tún jẹ́ Ọ̀gá àgbà fún abala ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Animal Science ní Fásitì Ìbàdàn. Bákan náà ni ó rún jẹ́ Alákòóso fún ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nípa ohun ọ̀gbìn àti ìdákosí (Dean, Faculty of Agriculture and Forestry) ní ọdún 1980 sí-1982. Ó tún jẹ́ Rector àkọ́kọ́ fún ilé-ẹ̀kọ́ College of Agriculture and Natural Resources, Bendel State tí ó ti di (Edo State) báyìí láàrín ọdún 1982-1984. Lákòótán , òun ni Giwá àgbà àkọ́kọ́ (First Dean and Deputy Vice-Chancellor) fún ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì Agriculture,Abẹ́òkúta.[3]

Àwọn ìtọ́ka sí àtúnṣe

  1. Empty citation (help) 
  2. 2.0 2.1 Empty citation (help) 
  3. 3.0 3.1 3.2 Empty citation (help)