Garrick Hagon
Garrick Hagon ( /ˈheɪɡən/; tí a bí ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 1939) jẹ́ òṣèré ọmọ orilẹ̀-èdè Britain àti Canada, ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Biggs Darklighter nínú Star Wars: A New Hope. Àpẹẹrẹ àwọn eré tí ó ti kópa ni Batman, Spy Game, Me and Orson Welles àti The Message. Òun ni ó kópa Ky nínú eré The Mutants, ó sì kópa Simon Gerrard, ọkọ Debbie Aldridge nínú eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Archers.
Garrick Hagon | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 27 Oṣù Kẹ̀sán 1939 London, England |
Iṣẹ́ | Actor |
Ìgbà iṣẹ́ | 1953–present |
Website | garrickhagon.com |
Ìpìlẹ̀ àti Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Hagon ní London, England, wọ́n sì tọ dàgbà ní Toronto, Ontario, Canada, níbi tí ó ti lọ ilé ìwé UTS àti Trinity College (Hon. English, 1963). Ó ṣeré pẹ̀lú Alec Guinness nínú eréRichard III ní Stratford Festival, èyí tí ó mú kí ó gba àmì-ẹ̀yẹ Tyrone Guthrie Award ní ọdún 1963.[1]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Garrick Hagon theatre profile". www.abouttheartists.com.