Gbólóhùn Ìtẹnumọ́

Gbólóhùn ìtẹnumọ́ (tí a tún mọ̀ sí I.T) jẹ́ Ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni a lè gbà ṣe ìtẹnumọ́ nínú èdè yorùbá. Àrokò tí a máa ń lò fún ọ̀rọ̀ ìtẹnumọ́ ni "IT".

Ọ̀nà láti ṣe ìtẹnumọ́ àkọ́kọ́

àtúnṣe

Ọ̀nà àkọ́kọ́ ni ṣíṣe ìgbésíwájú tàbí ìgbésẹ́yìn fún ọ̀rọ̀ tí a fẹ́ ṣe ìtẹnumọ́ fún nínú ẹ̀hun tàbí gbólóhùn.

Àpẹẹrẹ àkọ́kọ́

àtúnṣe

Àkàrà Òsú dún púpọ̀

Tí a bá fẹ́ ṣe ìtẹnumọ́ fún àkàrà Òsú tí ó wà nínú gbólóhùn náà tí a sì fẹ́ ṣe ìgbésíwájú fún un, yóò di :

Àkàrà Òsú, ó dùn púpọ̀ (IT + SOO + IṢ + EP)

Nínú gbólóhùn òkè yìí, a ṣe ìtẹnumọ́ fún "Àkàrà Òsú", a sì ṣe ìgbésíwájú fún un. Nǹkan mìíràn tí a tún ṣe àkíyèsí ni pé, a ṣe àfikún sílébù olóhùn òkè (SOO) sínú gbólóhùn náà.

A lè ṣe ìgbésẹ́yìn fún "Àkàrà Òsú" pẹ̀lú nínú gbólóhùn yìí.

Ó dùn púpọ̀, Àkàrà Òsú (SOO + IṢ + EP + IT)

Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, ọ̀rọ̀-ìṣe náà kò gba àbọ̀ ṣùgbọ́n ó gba ẹ̀pọ́n.

Àpẹẹrẹ kejì

àtúnṣe

Ọmọ kíláàsì wa di gómìnà ní Ìbàdàn.

A lè ṣe ìtẹnumọ́ fún "Ọmọ kíláàsì wá" tí ó wà nínú gbólóhùn náà.

Ọmọ kíláàsì wa, ó di gómìnà ní Ìbàdàn .(IT + SOO + IṢ + AB + EP)

Nínú gbólóhùn òkè yìí, a ṣe ìtẹnumọ́ fún "ọmọ kíláàsì wa" a sì ṣe ìgbésíwájú fún un, a sì ṣe àfikún sílébù olóhùn òkè (SOO) sínú gbólóhùn náà.

A lè ṣe ìgbésẹ́yìn fún "Ọmọ kíláàsì wa" pẹ̀lú nínú gbólóhùn yìí

Ó di gómìnà ní Ìbàdàn, ọmọ kíláàsì wa.(SOO + IṢ + AB + EP + IT)

Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, ọ̀rọ̀-ìṣe náà gba àbọ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni ó gba ẹ̀pọ́n.

Ọ̀nà láti ṣe ìtẹnumọ́ kejì

àtúnṣe

Ọ̀nà kejì tí a lè gbà ṣe ìtẹnumọ́ fún ọ̀rọ̀ ni nípa lílo atọ́ka ìtẹnumọ́ "ni". Ọ̀rọ̀ tí a bá fẹ́ ṣe ìtẹnumọ́ fún ni yóò wà níwájú tí atọ́ka ìtẹnumọ́ yóò sì tẹ̀lé e. A lè ṣe ìtẹnumọ́ fún olùwà, ọ̀rọ̀-ìṣe, àbọ̀ tàbí ẹ̀pọ́n inú gbólóhùn. Bí àpẹẹrẹ :

Adé jẹ iṣu ìyá Ọlá ní oko.

A lè ṣe ìtẹnumọ́ fún olùwà inú gbólóhùn náà báyìí :

Adé ni ó jẹ iṣu ìyá Ọlá ní oko.

A lè ṣe ìtẹnumọ́ fún ọ̀rọ̀-ìṣe inú gbólóhùn náà báyìí :

Jíjẹ ni Adé jẹ iṣu ìyá Ọlá ní oko.

A lè ṣe ìtẹnumọ́ fún àbọ̀ inú gbólóhùn náà báyìí :

Iṣu ìyá Ọlá ni Adé jẹ ní oko.

A lè ṣe ìtẹnumọ́ fún ẹ̀pọ́n inú gbólóhùn náà báyìí :

Ní oko ni Adé ti jẹ iṣu ìyá Ọlá.

Ọ̀nà láti ṣe ìtẹnumọ́ kẹta

àtúnṣe

Bákan náà ni a lè ṣe ìtẹnumọ́ fún odidi gbólóhùn nípa lílo atọ́ka ìtẹnumọ́ "ni" ní ìparí irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ :

Adé jẹ iṣu.

Tí a bá fẹ́ ṣe ìtẹnumọ́ fún un, yóò di:

Adé jẹ iṣu ni.


Adé jẹ iṣu ní oko.

Tí a bá fẹ́ ṣe ìtẹnumọ́ fún un, yóò di:

Adé jẹ iṣu ní oko ni.

Àwọn àrokò tí a lò

àtúnṣe

Ọ̀rọ̀-ìṣe = IṢ

Àbọ̀ =AB

Ẹ̀pọ́n= EP

Sílébù olóhùn òkè = SOO

Ìtẹnumọ́ = IT

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe