Gbólóhùn alákànpọ̀ ni èyí tí a fi ọ̀rọ̀ asopọ̀ so àwọn gbólóhùn mìíràn pọ̀ láti di ẹyọ kan. Àwọn ọ̀rọ̀ asopọ̀ tí a fi ń sọ gbólóhùn pọ̀ ni:

ṣùgbọ́n, tàbí/àbí, yálà.... tàbí, àmọ́, bẹ́ẹ̀ ni.

Ọ̀rọ̀ kan tún wà tí a máa ń lò bí ẹni pé ọ̀rọ̀ asopọ̀ ni. Ọ̀rọ̀ náà ni aṣáájú ọ̀rọ̀ ìṣe sì/dẹ̀ tí ìtumọ̀ rẹ̀ bá ọ̀rọ̀ asopọ̀ lọ, ṣùgbọ́n tí ìṣe sí rẹ̀ jẹ́ ti aṣáájú ọ̀rọ̀ ìṣe. Oríṣi gbólóhùn alákànpọ̀ mẹ́ta ni ó wà: oníṣọ̀kan, onílòdìsí àti apààrọ̀.

Oníṣọ̀kan

àtúnṣe

Gbólóhùn alákànpọ̀ oníṣọ̀kan ni èyí tí a so gbólóhùn méjì pọ̀ tí èrò wọn wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ara wọn. Àwọn wúnrẹ̀n tí wọ́n jẹ́ àbùdá gbólóhùn yìí ni - sì/dẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni...sì.

B.a - ó lówó; ó sì kọ́lé

ó ra aṣọ; ó sì wọ̀ ọ́

Oríṣi méjì ni gbólóhùn alákànpọ̀ oníṣọ̀kan. Oríṣi kìíní ni ajàjọgún nínú èyí tí gbólóhùn tí a so pọ̀ jàjọgún. Ọ̀nà tí a fi mọ èyí ni pé, a lè ṣe ìyípadà tẹ̀léǹtẹ̀lé àwọn gbólóhùn tí a so pọ̀ láìfa ìyàtọ̀ ìtumọ̀. Bí àpẹẹrẹ: Ó tóbi; ó sì sanra = ó sanra; ó sì tóbi

Oríṣi kejì ni aláijàjọgún nínú èyí tí tẹ̀léǹtẹ̀lé gbólóhùn tí a so pọ̀ kò ṣeé yípadà láìfa ìyàtọ̀ ìtumọ̀. Bí àpẹẹrẹ - ó ra búrẹ́dì; ó sì jẹ ẹ́ ¦ ó jẹ ẹ́; ó sì ra búrẹ́dì

Onílòdìsí

àtúnṣe

Gbólóhùn alákànpọ̀ onílòdìsí ni èyí tí a so gbólóhùn méjì pọ̀ tí èrò wọn lòdì sí ara wọn. Àwọn wúnrẹ̀n tí wọ́n jẹ́ àbùdá gbólóhùn yìí ni: ṣùgbọ́n, àmọ́ sì, bẹ́ẹ̀ ni, bẹ́ẹ̀ kọ...sì. Bí àpẹẹrẹ

Ó bímọ ṣùgbọ́n kò lọ́kọ

Ó lówó àmọ́ kò kọ́lé

Apààrọ̀

àtúnṣe

Gbólóhùn alákànpọ̀ apààrọ̀ ni èyí tí a so gbólóhùn méjì pọ̀ tí èrò wọn jẹ́ apààrọ̀ sí ara wọn. Àwọn ọ̀rọ̀ asopọ̀ tí a máa ń lò fún gbólóhùn yìí ni: tàbí/àbí, yálà..tàbí. Bí àpẹẹrẹ:

* Ẹ lè dúró dè wá tàbí kí ẹ máa lọ sílé.

Ó ṣeé ṣe kí a pa yálà...tàbí jẹ nínú gbólóhùn alákànpọ̀ apààrọ̀. Bí àpẹẹrẹ:

* Ẹ wá, ẹ ò wá, à á ṣe é.

Bí a ti tọ́ka sí i ṣáájú, nígbà tí àwọn gbólóhùn apààrọ̀ tí a so pọ̀ bá lódi sí ara wọn tàbí tí a bá ṣe àgékúrú tó bẹ́ẹ̀ tí tàbí/àbí bá fi bẹ̀rẹ̀ gbólóhùn, ìtumọ̀ ìbéèrè ni gbólóhùn alákànpọ̀ yìí máa ń ní. Bí àpẹẹrẹ:

Ó ti lọ àbí kò í tí ì lọ?

Ó tán tàbí ó kù?

Àbí ẹ fẹ́ẹ́ bá wa lọ?

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe