Georgina Onuoha
Òṣéré orí ìtàgé
Georgina Onuoha jẹ́ òṣèré Nollywood, afẹwàṣiṣẹ́, olóòtú ètò tẹlifíṣọ̀nù àti afowóṣàánú.[2] Ó wá láti Ìpínlẹ̀ Anámbra ní gúúsù ìla-òòrùn Nàìjíríà.. Ó darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ fíìmù ti Nàìjíríà ní ọdún 1990 nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá. Ṣùgbọ́n ó di gbajúmọ̀ ní ọdún 1992 lẹ́hìn kíkópa rẹ̀ nínu eré "Living in Bondage." Wọ́n yàán fún òṣèrè amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Africa Movie Academy Awards. Ní Ọdún 2016, ó fẹ̀họ́nú rẹ̀ hàn gbangba gbàngbà lóri ìgbésẹ̀ Ìjọba Nàìjíríà láti fi owó kuń owó epo pẹtiró.[3] Nínu ìfìwéránṣẹ́ Ínstágràmù rẹ̀ ní Oṣù Kẹẹ̀ta Ọdún 2016, ó jẹ́ kó di mímọ̀ wípé òun ti n bá àìsàn kan fàá láti bí ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn.[4]
Georgina Onuoha | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | September 29 [1] |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Naijiria |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 1990- di sin |
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Photos From Georgina Onuoha’s Birthday Party". iyodatv.com. Archived from the original on 22 August 2016. Retrieved 31 July 2016.
- ↑ "Nollywood Actress, Georgina Onuoha Shares Stunning Photos". informationng.com. Retrieved 31 July 2016.
- ↑ "Actress blasts President Buhari". pulse.ng. Archived from the original on 16 August 2016. Retrieved 31 July 2016.
- ↑ "For eight years I have battled illness – Georgina Onuoha [PHOTO]". dailypost.ng. Retrieved 31 July 2016.