Gidan Makama Museum Kano

 

Gidan Makama Museum Kano tàbí Kano Museum jẹ́ músíọ́ọ̀mù kan ní Ipinle Kano, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ilé yìí fìgbà kan jẹ́ ààfin ti Sarakunan Hausa (èyí tó jẹ́ ọba àwọn Hausa) ti Kano, ṣáájú ààfin tó wà níkàlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, ti Gidan Rumfa, ní sẹ́ńtúrì kẹẹ̀ẹ́dógún.[1] Músíọ́ọ̀mù yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́-ọnà tó lààmìlaaka àti àwọn nǹkan tó wúlò fún ìtàn tí ó tan mọ́ Kano, àti agbègbè rẹ̀.[2] Tí wọ́n ṣàwárí ní sẹ́ńtúrì kẹẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì dá mọ̀ bí i ilé ìrántí ti ìjọba Nàìjíríà.[3] Músíọ́ọ̀mù yìí pín sí àwòrán mọ́kànlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìdojúkọ rẹ̀. Díẹ̀ lára àwọn àwòrán yìí ni Zaure tàbí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé, pẹ̀lú ìṣàfihàn ohun èlò ìbílẹ̀, àwọn odi ìlú àti máàpù ìpínlẹ̀ Kano, ìtàn-àkọọlẹ̀ ti Kano, Kano ní sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún, ogun abélé, ètò ọrọ̀-ajé àti orin. [4]

Àyè kan náà sì ṣí sílẹ̀ nínú mùsíọ́ọ̀mù náà, tó dúró gẹ́gẹ́ bí ìpele iṣẹ́ fún ijó Koroso àti ẹgbẹ́ eré-oníṣe.[5]

Sẹ́ńtúrì kẹẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n kọ́kọ́ kọ́ ilé yìí, fún Muhammad Rumfa, tó jẹ́ ọmọ-ọmọ Ọba Hausa, tí wọ́n ṣẹ̀ fi jẹ Makama ti Kano nígbà náà. Rumfa pada jẹ ọba, ó sì kó lọ sí aàfin tuntun, àmọ́ àwọn Makama tí wọ́n wá fi jẹ lẹ́yìn ìgbà náà ń gbé ibẹ̀. Lẹ́yìn tí àwọn ìjọba amúnisìn gba ìlú Kano, ní ọdún 1903, iléyìí jẹ́ ibi tí àwọn aláwọ̀ funfun yìí ń gbé.[6]

Mùsíọ́ọ̀mù

àtúnṣe

Mùsíọ́ọ̀mù yìí wà ní òpópónà aàfin Emir, tí wọ́n sì pín sí àyè mọ́kànlá tó ní àwòrán, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan tí ó ní ohun-ọ̀ṣọ́ ìbílẹ̀ Kanawa, àwòrán, ohun-èlò orin, àti àwọn ohun nèlò lóríṣiríṣi.[7]

Àwọn àwòrán [6]

àtúnṣe

Díẹ̀ nínú àwọn ohun ìtàn tí wọ́n tọ́jú ní Gidan Makama

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Barau, Aliyu Salisu (2007) The Great Attractions of Kano. Research and Documentation Directorate Government House, Kano
  2. Nigerian Embassy
  3. "Make this summer vacation memorable for your kids". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-08-17. Archived from the original on 2021-03-03. Retrieved 2021-01-04. 
  4. Kano Online
  5. "Dance Draws Young Into Museum." Africa News Service 7 Jan. 2009. Business Insights: Global. Web. 5 Mar. 2016
  6. 6.0 6.1 "Nigeria: Gidan Makama - the Story of Kano's Famous Museum". Daily Trust. 23 December 2012. http://allafrica.com/stories/201212240983.html. Retrieved 5 March 2016. 
  7. "The Place of Gidan Makama and Gidan Dan Hausa in Tourism [opinion]." Africa News Service 29 July 2012. Business Insights: Global. Web. 5 Mar. 2016