Grace Ebor (tí wọ́n bí ní 8 August 1977) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó fìgbà kan jẹ́ eléré-ìdárayá tó máa ń sáré. Ó jáwé olúborí nínú eré ẹgbẹ̀rin mítà ní ìdíje 2003 All-Africa Games.

Grace Ebor ní ọdún 2002, tó ń gbáradì ní Calabar pẹ̀lú akẹgbẹ́ rẹ̀, ìyẹn Nwokeye àti Sooter

Àkọsílẹ̀ rẹ̀ tó dára jù ni 2:02.04 nínú ẹgbẹ̀rin mítà ní ọdún 2003 àti 4:28.17 ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (1500) mítà ní ọdún 2005.[1]

Àkọsílẹ̀ àwọn ìdíje rẹ̀

àtúnṣe
Ṣíṣe aṣojú fún   Nàìjíríà
2002 Commonwealth Games Manchester, United Kingdom 11th (sf) 800 m 2:03.65
16th (h) 1500 m 4:29.16
2003 All-Africa Games Abuja, Nigeria 1st 800 m 2:02.04
Afro-Asian Games Hyderabad, India 4th 800 m 2:07.10
2005 Universiade Izmir, Turkey 11th (sf) 800 m 2:06.63
16th (h) 1500 m 4:28.17
2006 African Championships Bambous, Mauritius 12th (h) 800 m 2:10.40

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Àdàkọ:World Athletics