Gráinne O'Malley[1] ( pípè rẹ̀ ní èdè Irish: [ɡɾˠaːn̠ʲə] 'Grawn-ya') (Àdàkọ:C. – c. 1603), tí wọ́n sì mò sí Grace O'Malley (Irish: Gráinne Ní Mháille, pronounced [gˠɾˠaːnʲə nʲiː waːlʲə]), jẹ́ olórí ìjọba Ó Máille tí ìwọ̀-oòrùn Ireland, àti ọmọ Eóghan Dubhdara Ó Máille.

Gráinne O'Malley
Grainne Mhaol Ni Mhaille statue
Westport House, in Westport, County Mayo
Orúkọ àbísọGráinne Ní Mháille
Ọjọ́ìbíc. 1530
Umhaill, Connacht, Ireland
Aláìsíc. 1603 (ọmọ ọdún 72–73)
most likely Rockfleet Castle, Ireland
Orúkọ mírànGrace O'Malley, Gráinne Mhaol, Granuaile
Iṣẹ́Land-owner, sea-captain, political activist
Olólùfẹ́
Àwọn ọmọEóghain Ó Flaithbertaigh, Murchad Ó Flaithbertaigh, Meaḋḃ Ní Fhlaithbertaigh, Tibbott Bourke
Parent(s)
  • Eóghan Dubhdara Ó Mháille (father)
  • Me Ní Mháille (mother)

Lẹ́yìn ìgbà tí bàbá rẹ̀ kú, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní máa ṣàkóso àwọn ilẹ̀ àti òkun, bí ó tilẹ̀ jẹ́pé ó ní ẹ̀gbọ́n ọkùnrin Dónal an Phíopa Ó Máille. Ìgbéyàwó tó ní pẹ̀lú Dónal an Chogaidh (Donal "of the war") Ó Flaithbheartaigh mú ọlá àti ipa ńlá bá a, ó ní ẹgbẹ̀rún màálù àti ẹṣin. Ní ọdún 1593, tí gómìnà àwọn Gẹ̀ẹ́sì Connacht, Sir Richard Bingham kó àwọn ọmọ rè ọkùnrìn Tibbot Bourke àti Murchadh Ó Flaithbheartaigh (Murrough O'Flaherty) àti ọbàkan rẹ̀ Dónal an Phíopa lẹ́rú, O'Malley wa ọkọ̀-ojú omi lọ sí England láti gbàwọ́n sílẹ̀. Ó ṣe àfihàn ohun tó fẹ́ sí Ọbabìnrin Elizabeth I ní ilé ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ní Greenwich Palace.

Wọ́n kò dárúkọ O'Malley nínú ìwé ọdọọdún ti àwọn Ireland, fún ìdí èyí, ìwé ìtàn nípa rẹ̀ sábà wá láti orísun àwọn Gẹ̀ẹ́sì, pàápàá jùlò ìbéèrè méjìdílógún "Articles of Interrogatory", àwọn ìbéèrè tí wọ́n kọ sí i ń orúkọ Elizabeth I.[2] Wọ́n dárúkọ rẹ̀ nínú ìwé àwọn Gẹ̀ẹ́sì àti ìwé ìtàn mìíràn bí i rẹ̀.[3]

Nínú àwọn ìtàn àwọn Ireland, Gráinne Mhaol ní wọ́n mọ̀ ọ́ sí tí ó sì jẹ́ aboni ní sẹ́ńtúrì kẹrìndílógún nínú ìtàn Ireland. Orúkọ rẹ̀ jáde nínú àwọn ìwé ìtan àwọn Gẹ̀ẹ́sì lóríṣiríṣi ọ̀nà, èyí tí Gráinne O'Maly, Graney O'Mally, Granny ni Maille, Grany O'Mally, Grayn Ny Mayle, Grane ne Male, Grainy O'Maly, àti Granee O'Maillie wà nínú rẹ̀,[4] wọ́n kìí sábà pè ní Grace O'Malley.[5] "The Pirate Queen" ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀yà máa ń pè é

Àwọn ìtọ́kasí.

àtúnṣe
  1. Àdàkọ:Cite ODNB
  2. See the supplement to Chambers, 2003.
  3. Lambeth Palace Library, ms. no 601, p. 10, cited in Chambers 2003, p. 85
  4. Chambers 2003, p. 39
  5. There is only one instance recorded in Chambers in Chapter Nine End of an Era where she is referred to in a dispatch as Grace O'Malley