Hamoud Boualem
Hamoud Boualem jẹ́ ohun mímu tí ilé-iṣẹ́ Algerian gbé jáde ,tí ó ń ṣe àgbéjáde ohun mímu tí ó gbajúmọ̀ ní Algeria tí ó sì ń di kíkó lọ sí France, United Kingdom, àti Canada. Tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1878 pẹ̀lú Ilé-iṣẹ́ rẹ àkọ́kọ́ ní agbègbè Belcourt ti Algiers, ó wà lára àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó dàgbà jù ní orílẹ̀-èdè.[1] Àwọn ọjà rẹ̀ ni sodas bí "Selecto", "Hamoud", "Slim" (ní orísìírísìí adùn), àti orísìírísìí adùn ti olómi. Ilé-iṣẹ́ gbogbogbò rẹ̀ wà ní ààrin gbùngbùn Algiers.
Founder(s) | Boualem Hamoud |
---|---|
Industry | Beverages |
Total assets | 900 |
Subsidiaries | Lion in Boufarik
Dhaya in Sidi Bel Abbès Alma in Ouzellaguen |
Ìtàn
àtúnṣeYoussef Hammoud, adùn tí àwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ se, tí ó wà ní agbègbè Belcourt tí ó sì sẹ̀dá lemonade La Royale, bàbáńlá ti àpẹẹrẹ Hamoud la Blanche. La Royale, tí a se láti ara òrom̀bó tí a fi ọwọ́ ṣe àṣàyàn rẹ̀, gba àmì ẹ̀yẹ, tí a kà sí Hors concours, ní Paris World Fair ní ọdún 1889. Ó padà gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ góòlù àti sílíbà. Ní ọdún 1907,wọ́n ṣe àfikún Victoria, ápù aláwọ̀ búráùn àti adùn. Ohun mímu yìí, tí a mọ̀ sí SELECTO lónìí , jẹ́ ọ̀kan lára ìdámọ̀ iyì Algerian.[2]
Ní ọdún 1920, Boualem Hammoud, ọmọ-ọmọ Youssef, fi orúkọ ilé-iṣẹ́ náà sílẹ̀ ó sì yí orúkọ ilé-iṣẹ́ náà padà láti Hamoud & Sons sí Hamoud Boualem & Cie. Ní ọdún yẹn, ilé-iṣẹ́ náà di kíkó lọ sí Hassiba Ben Bouali Street,[3] ní báyìí ọ́fíìsì gbogbogbò fún ilé-iṣẹ́ náà. Nígbà tó yá, Hamoud Boualem ṣe ìfilọ́lẹ̀ ohun mímu lábẹ́ Slim label pẹ̀lú àkọmọ̀nà "Slim, le citron qui prime." Lónìí, ilé-iṣẹ́ Slim ní adùn márùn-ún (lemon, orange, green apple, pineapple àti bitter).
Mọ̀lẹ́bí Hamoud àti Hafiz darapọ̀ , ilé-iṣẹ́ náà sì di LLC.[4] Ní ọdún 2003, Hamoud Boualem sọ di ọ̀tun ṣíṣe rẹ̀ tí ó sì ṣe ìfilọ́lẹ̀ ọ̀nà PET èyí tí ó ṣe àmúpé ìwọ̀n ìpadà gíláàsì rẹ̀. Ilé-iṣẹ́ náà náà ń gbèèrú síi ní ṣíṣí sí ọjà ìkólọsókèòkun. Ìfijoyè ilé-iṣẹ́ tuntun rẹ̀ ní Boufarik (wilaya of Blida) láti ba à lè ṣe àlékún ìwọ̀n ìgbéjáde rẹ̀ àti láti ba à lè pèsè fún bíbéèrè rẹ̀.[5]
Agolo náà di fífi lọ́lẹ̀ ní ọdún 2017, èyí tí ó mú dídán àti ìyàtọ̀ bá ilé-iṣẹ́ èyí tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún. Ní ọdún 2018, Hamoud Boualem se ìfilọ́lẹ̀ Lim ON, ohun mímu titun ni pẹ̀lú ohun mímu eléso, wà ní orísìí adùn mẹ́ta: Citrus, Orange pulp àti Mojito. Ní ọdún 2020, PET di ṣíṣe ìfilọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n 33cl àti 1L.
Àwọn ọjà
àtúnṣeHamoud Boualem ní orísìírísìí ìwọ̀n ohun mímu tí ó ti fẹsẹ̀rinlẹ̀ ní àwọn ilé àti jù bẹ́ẹ̀ lọ ní Algerian. Díẹ̀ nínú àwọn ọjà ilé-iṣẹ́ náà tí ó gbajúgbajà ni ìwọ̀nyí:
- Selecto: omi ọsàn a-mú-ọ̀fun-tutù tí ó ti di ìfẹ́ràn ìrandíran.[6]
- Hamoud: Ohun mímu tí ó máa ń bá àwọn ohun mímu káàkiri àgbáyé figa-gbága.[7]
- Slim: Wà ní orísìírísìí adùn èso, Slim ṣe ìpèsè fífúyẹ́ àti adùn sí àwọn ohun mímu ìbílẹ̀.[8]
- Lim ON: Àfikún tuntun sí mọ̀lẹ́bí Hamoud Boualem family, Lim ON jẹ́ ohun mímu tí ó ń pèsè adùn àti ìrẹ̀ǹgbẹ.
Ipa àṣà
àtúnṣeHamoud Boualem ti di ìkan náà pẹ̀lú àṣà Algeria ó sì sábàá máa ń di síso mọ́ àti ìṣe. Àwọn ọjà ilé-iṣẹ́ náà ní ààyè pàtàkì ní ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ará ilẹ̀ Algerians, tí ó ń mú ìrántí ìgbà èwe padà wá àti àpéjọ mọ̀lẹ́bí.[9]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Hamoud Boualem: Algerian soft drink company that kept Coca-Cola and PepsiCo at bay" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2024-02-28. Retrieved 2024-06-11.
- ↑ Mansari, Kamel (2024-04-03). "Exposition « D'Art el Gazouz » : L'héritage de Hamoud Boualem revisité". Le Jeune Indépendant (in Èdè Faransé). Retrieved 2024-07-13.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:02
- ↑ "Algérie : l’incroyable saga de Hamoud Boualem, fabricant du Selecto - Jeune Afrique.com". JeuneAfrique.com (in Èdè Faransé). Retrieved 2024-07-13.
- ↑ "HAMOUD BOUALEM". Pages Maghreb (in Èdè Faransé). Retrieved 2024-07-13.
- ↑ "Selecto, un goût unique et inimitable". Hamoud Boualem (in Èdè Faransé). Archived from the original on 2024-07-13. Retrieved 2024-07-13.
- ↑ "Hamoud La Blanche, la boisson citronnée incontournable". Hamoud Boualem (in Èdè Faransé). Retrieved 2024-07-13.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Slim". Hamoud Boualem (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-07-13.
- ↑ Mediapart, La rédaction de (2024-07-13). "Sodas du peuple". Mediapart (in Èdè Faransé). Retrieved 2024-07-13.