Hans Joachim Morgenthau (February 17, 1904 – July 19, 1980) je omo Germany ara Amerika] to je ikan ninu asiwaju ninu igbeka oselu akariaye ni orundun ogun. O se ipa pataki si irojinle awon ibasepo akariaye ati igbeka ofin akariaye, be sini iwe re Politics Among Nations, (Oselu Larin awon Orile-ede) to koko je titejade ni 1948, je eyi to je lilojulo ni awon yunifasiti ni Amerika ninu papa eko re. Bakanna, Morgenthau tun kowe pupo nipa oselu akariaye ati lori iselu okere orile-ede Amerika ninu awon iwe onideede bi The New Leader, Commentary, Worldview, ati The New Republic. O mora be sini o sore pelu opo ninu awon omowe asiwaju ati olukowe igba aye re bi Reinhold Niebuhr, George F. Kennan, ati Hannah Arendt. Lasiko kan ni bere Ogun Alasiri, Morgenthau je oludamoran fun Ile-Ise Oro Okere Amerika nigbati Kennan je olori Ibise Eto Iselu re. Fun opo igba isese re Morgenthau je olugbewo olomowe iselu okere Amerika ju bi oluda re lo. Ooto nipe o lodi si ikopa Amerika ni Vietnam.