Heaven's Hell
Theatrical release poster
Directed by Katung Aduwak
Written by Tenyin Ikpe Etim

Uyai Ikpe Etim

Produced by Katung Aduwak

Tenyin Ikpe Etim

Starring
  • Nse Ikpe Etim
  • Fabian Adeoye Lojede
  • Bimbo Akintola
  • Chet Anekwe
  • Damilola Adegbite
  • OC Ukeje
  • Kalu Ikeagwu
  • Femi Jacobs
  • Bimbo Manuel
  • Gideon Okeke
Cinematography Jeffrey Smith

Matthew Sleboda

Edited by Sammie Amachree
Music by Tola Adeogun

Triumph 'Tyrone' Grandeur

Production

companies

One O Eight Media

BGL Asset Management Ltd

Hashtag Media House

Distributed by Genesis Distribution
Release date
  • 10 May 2019
Running time 95 minutes
Country Nigeria
Language English

Heaven's Hell jẹ́ fíìmù Nàìjíríà tí ó ní ṣe pẹ̀lú bí ènìyàn ṣe máa ń wùwà,tí Katung Aduwak gbé jáde tí ó sì dárí rẹ̀ ní ọdún 2019; àwọn òṣèré tí ó kópa nínú rẹ̀ : Nse Ikpe Etim, Fabian Adeoye Lojede, Bimbo Akintola, Chet Anekwe, Damilola Adegbite, OC Ukeje, Kalu Ikeagwu, Femi Jacobs, Bimbo Manuel àti Gideon Okeke. BGL Asset Management Ltd àti One O Eight Media ni àwọn tí ó ná owó si. Àwọn akẹgbẹ́ tí ó ran ìgbé jáde rẹ̀ lọ́wọ́ ni Hashtag Media House àti Aberystwyth University.

Fíìmù yìí ,tí ìtàn ìgbésí ayé ènìyàn kan mú ìmísí rẹ̀ wá , ni a ṣe ní ìlú Èkó tí ó sì ń sọ ìtàn àwọn ìyàwó ilé méjì tí òkun ọ̀rẹ́ wọn kò ṣeé já ṣùgbọ́n tí ó kún fún ẹ̀tan àti ìdàlẹ̀ ; láàrin òkùnkùn tí ó borí àjọṣepọ̀ wọn pẹ̀lú ọkọ wọn . 23rd January 2015 ni wọ́n fi ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ sí tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n dáa dúró nítorí àwọn òfin tí ó máa ń de ìgbéjádé. 10th May 2019 ni wọ́n padà gbé e jáde


Àwọn òṣèré [edit source]

àtúnṣe
  • Fabian Adeoye Lojede ni Edward Henshaw
  • Nse Ikpe Etim ni Alice Henshaw
  • Chet Anekwe ni Jeff Aliu
  • Bimbo Akintola ni Tsola Aliu
  • Damilola Adegbite ni Janet Cole
  • OC Ukeje ni Ahmed
  • Kalu Ikeagwu ni Efosa Elliots
  • Gideon Okeke ni Akanimo
  • Femi Jacobs ni Detective Popoola
  • Bimbo Manuel ni Chief Justice
  • Katherine Obiang ni Tara
  • Linda Ejiofor ni Secretary
  • Waje Iruobe ni Estate Agent


Ìgbéjáde[edit]

àtúnṣe

Heaven’s Hell ni a rí bíi fíìmù tí ó ń gbèrò láti dojú kọ ìwà ipá lòdì sí àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé. Aduwak sọ wípé : "...ní agbègbè yìí ní àgbáyé ,a sì ń fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ìwà ipá nínú ilé . Ní pàtàkì , mo fẹ́ kí fíìmù yìí ,Heaven’s Hell gba àwọn ènìyàn sílẹ̀. Mo fẹ́ kí ó ru ẹnìkan sókè láti kúrò nínú ìbáṣepọ̀ tí kò dára . [..] Ipa tí ó bá lè kó láti mú kí ayé tí a wà yí túbọ̀ dára si". Ọdún kan ni wọ́n tó ṣe ìpìlẹ̀ fíìmù yìí , lẹ́yìn èyí ni ìyàwó rán gbòógì bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹsàn-án ,oṣù kẹrin ọdún 2013 ní ìlú Èkó pẹ̀lú àwọn òṣèré tí ó kó ipa tí ó pọ̀ jù. Abala díẹ̀ nínú fíìmù yìí ni a yà ní ìlú Èkó ní Kirikiri Maximum and Medium Security Prisons. Yíya fíìmù yìí ní ìlú Èkó gbà ju ọ̀sẹ̀ mẹ́ta , lẹ́yìn èyí ni wón lọ sí Wales, níbi tí wọ́n ti ya àwọn abala mìíràn. Sony F55 cameras ni wọ́n fi ya fíìmù yìí , and the film's production was led tí Jeffrey Smith sì dárí ìgbé jáde rẹ̀.BGL Asset Management Ltd & One O Eight Media ní ó jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn tí ó ná wó sí fíìmù yìí , Hashtag Media House, àti Aberystwyth University gẹ́gẹ́bí àwọn olùbáṣiṣẹ́pọ̀ tí ó ran yíya fíìmù náà lọ́wọ́.


Orin[edit source]

àtúnṣe

Orin tí a lò nínú fíìmù yìí tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ "3rd World War", ni Jesse Jagz àti Femi Kuti ṣe ,7th August 2013 ni wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀


Promotions and release[edit source]

àtúnṣe

Ìpàdé fún fíìmù yìí wáyé ní ọjọ́ kẹjọ , oṣù kẹrin ọdún 2013, ní Clear Essence, Ikoyi, Lagos, ní bí tí wọ́n tí fi léde wípé , fíìmù náà yóò jáde ní ìlà kẹta ọdún 2013. Àgbéjáde fíìmù náà ni wọ́n padà sún síwájú nítorí ìdí tí a kò mọ̀. Ní oṣù Kejìlá ọdún 2014, FilmOne fi léde wípé fíìmù náà yóò jáde ní ọjọ́ kẹtàlélógún,Oṣù Kínní ọdún 2015. Àjọ Nigerian Films and Video Censor Board ni ó da á dúró nítorí àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀ tí wọ́n pè ní "explicit and inciting content". Àwọn tí ó ṣe fíìmù náà ni wọ́n gbà níyànjú pé kí wọ́n lọ tún fíìmù náà ṣe kí wọ́n tó lè gbé e jáde . FilmOne ni ó ṣe alágbàtà fíìmù yìí tẹ́lẹ̀ , ṣùgbọ́n Genesis Distribution ni ó wá ń ṣe alágbàtà rẹ̀ báyìí . Ọjọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún ọdún 2019 ní wón tó wá gbé e jáde.


References[edit source]

àtúnṣe
  1. ^
  2. ^
  3. ^
  4. ^ Jump up to:a b c d
  5. ^ Jump up to:a b
  6. ^ Jump up to:a b
  7. ^ Jump up to:a b c
  8. ^
  9. ^ Jump up to:a b
  10. ^ Jump up to:a b c
  11. ^
  12. ^
  13. ^
  14. ^
  15. ^
  16. ^
  17. ^


àtúnṣe