Henry Townsend (missionary)
Henry Townsend (tí a bí ní ọdún 1815, tí ó sì kú ní ọdún 1886) jẹ́ ajíǹhere ti ìjọ Anglican ní orílè-èdè Nàìjíríà. Wọ́n fi àmì-òróró yàn án ní ìlú England, ní ọdún 1842. Ọdún kan náà ni Townsend lọ sí Sierra Leone. Lẹ́yìn tí ó ṣiṣẹ́ níbè fún oṣù díẹ̀, wọ́n gbe lọ sí ilẹ̀ Yoruba.[1]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeLáti ọdún 1846 wọ ọdún 1867, ìlú Abẹ́òkúta ni wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn. Thomas Birch Freeman ni aláwọ̀ funfun àkọ́kọ́ tó wọ ilẹ̀ Abẹ́òkuta. Ó dé síbẹ̀ ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kejìlá, ọdún 1843. NÍgbà tí ó dé sí ilè Badagry ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kejìlá, ó ṣalábàápàdé òjíṣẹ́ Ọlọ́run Henry Townsend, wọ́n sì jọ ṣàjọyọ̀ ọdún Kérésì. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ajisafe sọ, Townsend ni aláwò-funfun àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ wọ ilè Abẹ́òkuta ní ọjọ́ kẹrin oṣù kìíní, ọdún 1843, tí wọ́n sì fun ní ìgbàlejò ńlá (Ajisafe 1924: 85). Látàri ṣíṣe iṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Samuel Crowther, tó jé ọmọ Yoruba àti ajíhìnrere ní ìjọ Aguda, Townsend kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orin inú ìwé ní Yorùbá. Láti ọdún 1871 wọ ọdún 1872, Henry àti Mrs Townsend jẹ́ ọ̀gá ilé-ìwé àgbà fún ilé-ìwé CMS Female Institution ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà. Henry Townsend fẹ̀hìntì ní ọdún 1876.[2]
Henry Townsend ṣe àtẹ̀jáde ìwé-ìròyìn Yorùbá ní ọdún 1859. Èyí ni ó bí iṣẹ́ atẹ̀ròyìn jáde ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òun sì ni ìwé-ìròyìn elédè méjì àkọ́kọ́. Ó lo ọdún méjọ kó tó kú.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Henry Townsend (1820-1885)". RAMM. 2022-05-20. Retrieved 2023-02-03.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Henry Townsend: A visionary leader - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2019-12-08. Archived from the original on 3 February 2023. Retrieved 2023-02-03.