Hepataitisi A (tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ sí àjàkálẹ̀ hepataitisi) jẹ́ àjàkálẹ̀ àrùn kan tó jẹ́ ara àwọn àìsàn-kẹ̀kẹ̀ tó máa n bá ẹ̀dọ̀ jà èyí tí kòkòrò-àrùn hepataitisi A {HAV} máa n tàn kálẹ̀.[1] Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àìsàn yìí máa n farahàn fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tàbí kí ó má tilẹ̀ farahàn rárá pàápàá júlọ̀ lára àwọn ọ̀dọ̀.[2] Láàrin ìgbà tí ẹnìkan kó àìsàn náà sí àkókò tí yóò farahàn máa n tó bí i ọ̀ṣ̀ẹ̀ méjì sí mẹ́fà .[3] Fífarahàn àìsàn náà máa n sáábà gbà tó ọ̀ṣẹ̀ mẹ́jọ, tí ó sì máa n wá pẹ̀lú ọkàn-rínrìn, èèbì, ìgbẹ̀-gbuuru, awọ-ara bí-àyìnrín,ibà àti inú rírun.[2] Ìmọ̀lára-àìsàn yìí máa n wá lemọ́lemọ́ lára bí i ìdá mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀dógún ninu ọgọ́rùn ún ènìyàn láàrin oṣù mẹ́fà lẹ́hìn tí àìsàn náà bá ti kọ́kọ́ kọluni.[2] Àìsàn-kẹ̀kẹ̀ tí-n-mú-ẹ̀dọ̀ ṣíwọ́-iṣẹ́ kí í sáábà bá ìmọ̀lára yìí rìn nítorí tí ó wọ́pọ̀ júlọ láàrin àwọn àgbàlagbà.[2]

Hepataitisi A
Hepataitisi AA case of jaundice caused by hepatitis A
Hepataitisi AA case of jaundice caused by hepatitis A
A case of jaundice caused by hepatitis A
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10B15. B15.
ICD/CIM-9070.0, 070.1 070.0, 070.1
DiseasesDB5757
MedlinePlus000278

Jíjẹ oúnjẹ tàbí mímu omi tí ìgbẹ́ alarùn kan ti ṣe àkóbá fún ni ó máa n tan àìsàn náà kálẹ̀ .[2] Ẹja-oníkarawun tí a kò bá ṣè jinná dáadáa tún jẹ́ orísun okùnfà tó wọ́pọ̀ fún àìsàn yìí.[4] Ó sì tún lè jẹ nípasẹ̀ fífi ara kan ẹni kan tí ó ní àìsàn náà lára.[2] Bí ó tilẹ jẹ́ pé ni ọ̀pọ̀ ìgbà ni kì í hán lára àwọn ọmọdé bí wọn bá ní àìsàn náà lára, síbẹ̀ wọn lè ko ran ẹlòmíràn .[2] Lẹ́yìn tí àìsàn náà bá sì ti ṣe ẹnìkan lẹ́ẹ̀kan, kò tún ní í lè nípá lórí ẹni náà mọ́.[5] Ṣíṣe àyẹ̀wò àìsàn náà nílò pé kí a ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ nítorí tí àìsàn náà farapẹ́ irúfẹ́ àwọn àìsàn bẹ́ẹ̀.[2]  Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn kòkòrò-àrùn hepataitisi márùn ún tí a mọ̀: A, BCD, àti E.

 Abẹ́rẹ́-àjẹsára hepataitisi A lágbára tó láti dènà àìsàn yìí.[2][6] Àwọn orílẹ̀-èdè míràn ṣe é ní dandan pé kí àwọn ọmọdé àti àwọn tí àìsàn yìí lè tètè kọlù máa gbà àjẹsára yìí lóòrèkórè.[2][7] Ó jọ pé àjẹsára náà máa n ṣiṣẹ́ lára títí láí ni.[2] Àwọn ìgbésẹ̀ yòókù tí a tún lè fi dènà rẹ̀ ni fífọ-ọwọ́ àti ṣíṣe oúnjẹ wa ní àṣèjínna.[2] Kò fẹ́rẹ̀ sí ìtọ́jú kan ní pàtó, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsinmi tí ó tó àti lílo òògùn ní bí a ṣe kọ ọ́ fún ní gẹ́lẹ́ n ṣiṣẹ́ fún ọkàn-rìnrìn tàbí ìgbẹ́-gbuuru.[2] Àìsàn náà sì máa n lọ pátápátá láì ṣe àkóbá fún ẹ̀dọ̀ .[2] Tí wàhálà ẹ̀dọ̀ tó-ṣíwọ́-iṣẹ́ bá ṣẹlẹ̀, ọ̀nà-àbáyọ kan ṣoṣo náà ni gbígba-ẹ̀dọ̀-míràn.[2]

Káàkiri àgbáyé, bí i miliọnu kan àbọ̀ ènìyàn ni àìsàn yìí n bá fínra lọ́dọọdún[2] èyí tí ó jẹ́ díẹ̀ lára ọ̀kẹ̀ àìmọye tí àìsàn náà kọlù lápapọ̀.[8] Àwọn ẹkùn tí ìmọ́tótó kòsí àti tí àwọn ibi ti omi tó mọ́ kò ti pọ̀ ni àìsàn náà ti wọ́pọ̀ ní àgbáyé.[7]  Ní bí i ìdà àádọ́rùn ún nínú ọgọ́rùn ún àwọn ọmọdé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó-ṣẹ̀ṣẹ̀-n-dìde-nlẹ̀ ni àìsán yìí ti ṣe wọn lati bí i ọmọ ọdún mẹ́wàá, tí ara wọn sì kọ̀ ọ́ ní ipò àgbà.[7] Ó tún máa n sáábà bẹ́ ṣílẹ̀ bí àjàkálẹ̀ àrùn ní àwọn orílẹ̀-èdè tí n gòkè-àgbà lọ́wọ́ níbi tí àìsàn náà kò ti ṣe àwọn ọmọ náà ní èwe tí abẹ́rẹ́ àjẹsára kò sì tún kárí níbẹ̀.[7] Ní ọdún 2010, àìsàn hepataitisi A tó kanpá yọrí sí ikú àwọn 102,000 ènìyàn.[9] Àyájọ Hepataitisi L’ágbàáyé máa n wáyé ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù keje lọ́dọọdún láti ṣí àwọn ènìyàn létí sí kòkòrò-àrùn hepataitisi.[7]

References

àtúnṣe
  1. . 
  2. 2.00 2.01 2.02 2.03 2.04 2.05 2.06 2.07 2.08 2.09 2.10 2.11 2.12 2.13 2.14 2.15 Matheny, SC; Kingery , JE (1 December 2012). "Hepatitis A.". Am Fam Physician  86 (11): 1027–34; quiz 1010–2. PMID 23198670 . http://www.aafp.org/afp/2012/1201/p1027.html. 
  3. . 
  4. . March 2013 . 
  5. The Encyclopedia of Hepatitis and Other Liver Diseases. Infobase . 2006. p. 105. ISBN 9780816069903. http://books.google.ca/books?id=HfPU99jIfboC&pg=PA105. 
  6. . 
  7. 7.0 7.1 7.2 7.3 7.4 "Hepatitis A Fact sheet N°328". World Health Organization. July 2013. Retrieved 20 February 2014. 
  8. Wasley, A; Fiore, A ; Bell, BP  (2006). "Hepatitis A in the era of vaccination.". Epidemiol Rev  28: 101–11. doi:10.1093/epirev/mxj012 . PMID 16775039 . http://epirev.oxfordjournals.org/content/28/1/101.long. 
  9. Lozano, R (Dec 15, 2012). "Global and regional mortality from 235 causes of death for 20 age groups in 1990 and 2010: a systematic analysis for the Global Burden of Disease Study 2010". Lancet 380 (9859): 2095–128. doi:10.1016/S0140-6736(12)61728-0. PMID 23245604.