Honey Care Africa
Honey Care Africa jẹ́ àjọ kan tí wọ́n dá kalẹ̀ ní ọdún 2000 láti sàtìlẹ́yìn fún ìṣe sísìn oyin ní Ìlaòrùn Áfríkà. Wọ́n tí ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé isé aládàáni àti ìjọba àwọn orílẹ̀ èdè bi Kenyaàti Tanzania, Honey Care ma ń pèsè owó àti ìdánilẹ́kọ́ fún àwọn ènìyàn tí ó bá fẹ́ kó nípa sísin oyin. Honey Care tún ma ń pèsè ọjà fún oyin fún àwọn tó bá fẹ́ ta oyin ní iye tí wọ́n ti ma rí èrè. Wọ́n ma ń ra oyin nínú oko ti wọ́n sì ń san owó fun, lẹyìn èyí, wọn ma ta àwọn oyin yìí fún àwọn ilé isé tí ó bá fẹ́ rà. Ẹgbẹ́ yìí gbajúmọ̀ ní ìlà oòrùn Áfríkà.
Àwọn àmì-ẹ̀yẹ
àtúnṣeHoney Care Africa àti àwọn adarí rẹ̀ ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ, àwọn bi:
- the Equator Initiative Prize ní World Summit on Sustainable Development (2002)
- the International Development Marketplace Innovation Award in partnership with Africa Now from the World Bank & Soros Open Societies Institute (2002)
- the World Business Award from the Prince of Wales International Business Leaders Forum and United Nations Development Programme (2004)
Honey Care Africa ti ṣe ètò lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ rédíò àti Mídíà bi BBC, the Chicago Tribune, The Globe and Mail, Financial Times, CNBC Europe, CBC, UN Radio, Daily Nation, àti East African Standard.