Honeydew melon jẹ́ ọ̀kan lára méjì nínú gbòógì oríṣi èso tí a yàn gbìn ní ọ̀wọ́ èso Cucumis melo Inodorus.[1] Àbùdà a rẹ̀ jẹ́ èyí tí ó nípọn, tí ó dán, tí kò sí ní òórùn dídùn. Èyí tó jé èkejì nínú ọ̀wọ́ yìí ni wrinkle-rind casaba melon.[2]

Honeydew melon, Kolkata, West Bengal, India
Honeydew melon flower
Honeydew melon flower

Àbùdá àtúnṣe

Honey dew ní àbùdá roboto, ó sì gùn ní ìwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí mejìlélógún sẹ̀ǹtímítà. Ní kárí, ó máa ń gbé ìwọ̀n kílógírámù 1.8 sí 3.6.[3] Èèpo rẹ̀ máa ń jẹ́ àwọ̀ ewéko fẹ́rẹ́fẹ́, tí èpò dídán rẹ̀ sì máa ń jẹ́ yálà àwọ̀ ewéko tàbí ti ìtànná òrùn. Bí i àwọn èso tó kù, èso yìí máa ń ní kóro. A máa ń jẹ tínu èso yìí, lọ́pọ̀ ìgbà lẹ́yìn oúnjẹ, àti pé a tún le rí i ní àwọn ilé-ìtajà káàkiri lágbàáye. Ní California, honey dew máa ń wà láàrin osù kẹjọ sí oṣù kẹwàá.[4]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. Stephens, James M. (2018-11-01). "Melon, Honeydew—Cucumis melo L. (Inodorus group)". Minor Vegetables Handbook. University of Florida, Institute of Food and Agricultural Sciences Extension. Retrieved 2021-01-25. 
  2. Stephens, James M. (2018-11-01). "Melon, Casaba—Cucumis melo L. (Inodorus group)". Minor Vegetables Handbook. University of Florida, Institute of Food and Agricultural Sciences Extension. Retrieved 2021-01-25. 
  3. A Comprehensive Visual Guide: What Does a Honeydew Melon Look Like and How to Identify It. What Does a Honeydew Melon Look Like: A Visual Guide.
  4. Honeydews Archived 2017-05-06 at the Wayback Machine.. Producepete.com. Retrieved on 2015-04-22.