Hortavie Mpondo (tí wọ́n bí ní 27 Oṣù Kẹfà, Ọdún 1992) jẹ́ òṣèrébìnrin, apanilẹ́rìn-ín, àti afẹwàṣiṣẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù.

Hortavie Mpondo
Ọjọ́ìbíHortavie Lydie Sengue Mpondo
Oṣù Kẹfà 27, 1992 (1992-06-27) (ọmọ ọdún 31)
Limbe, Cameroon
Orílẹ̀-èdèCameroonian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Douala
Iṣẹ́Actress, model
Ìgbà iṣẹ́2017-present

Ìsẹ̀mí rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Mpondo ní ìlú Limbe, orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù ni ́ọdún 1992. Ó lọ sí ilé-ìwé College Sonara fún ètò ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Ní ọdún 2010, Mpondo lọ sí ìlú Douala láti kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ biochemistry láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga University of Douala.[1] Àwọn òbí rẹ̀ wọn kò ba faramọ́ ààyò iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ pẹ̀lú ìpinnu láti jẹ́ kó di ọ̀mọ̀wé.[2]

Mpondo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi afẹwàṣiṣẹ́ tó sì ti ṣe ìpolówó fún ilé-ìtajà BoldMakeUp. Ó tún ti ṣe ìpolówó fún ilé-iṣẹ́ BGFIBank Group ní Kamẹrúùnù.[3] Ní ọdún 2017, ó kópa níbi ètò Deidoboy Fashion Day, èyí tí ó wáyé ní Alfred Saker College ní agbègbè Deïdo ní ìlú Douala pẹ̀lú àwọn gbajúmọ̀ míràn bíi Tchop Tchop, ẹni tí n ṣe ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn atọ́kùn ètò tẹlifíṣọ̀nù ní orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù.[4]

Ní ọdún 2017, ó pinnu láti gbájúmọ́ ṣíṣe sinimá àgbéléwò. Ní ọdún náà, Mpondo kó ipa Amanda nínu eré Le Coeur d'Adzaï, èyí tí àwọn olùdarí rẹ̀ jẹ́Stéphane Jung àti Sergio Marcello.[3] Ó kó ipa Samira, ọmọbìnrin àgbà olóyè kan nínu eré oníṣókí ti Therry Kamdem kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Elles ní ọdún 2018. [5] Ní ọdún 2019, ó kó ipa Morelia nínu eré oníṣókí kan tí Dante Fox ṣe tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Solo Girl.[6] Ó sọ di mímọ̀ wípẹ́ ipa ọ̀ún ni ó pe òun níjà jùlọ.[2] Mpondo kó ipa olú-ẹ̀dá-ìtàn nínu eré aláwàdà afìfẹ́hàn kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Coup de foudre à Yaoundé, tí olùdarí eré náà síì n ṣe Mason Ewing, ẹnití ó ti pàdánù ojú rẹ̀.[7]

Yàtọ̀ sí ṣíṣe iṣẹ́ òṣèré àti afẹwàṣiṣẹ́, Mpondo tún maá n ṣiṣẹ́ aṣàpẹẹrẹ àwòrán.[2]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀ àtúnṣe

  • 2017 : Le Coeur d’Adzaï as Amanda
  • 2018 : Elles as Samira (short film)
  • 2018 : Le Prince de Genève as Raïssa (short film)
  • 2018 : Otage d’amour as Sylvie (TV series)
  • 2019 : The Solo Girl as Morelia (short film)
  • 2019 : La Parodie du Bonheur as Maelle (short film)
  • 2019 : Coup de foudre à Yaoundé as Rose Young
  • 2020 : Madame...Monsieur (TV series)

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Hortavie Mpondo, La releve est assuree" (in French). Douala Bouge: pp. 26-27. November 22, 2019. https://issuu.com/doualabouge/docs/magazine-sept-oct-nov-2019-final. Retrieved 1 November 2020. 
  2. 2.0 2.1 2.2 "Hortavie Mpondo: Des Sciences Au Petit Echran" (in French). Septieme Magazine. May 2020. https://septiememagazine.files.wordpress.com/2020/05/septieme_mai-2020-1.pdf. Retrieved 1 November 2020. 
  3. 3.0 3.1 "PEOPLE : HORTAVIE MPONDO, UNE ACTRICE QUI A DU POTENTIEL" (in French). Le Film Camerounais. 29 June 2018. https://lefilmcamerounais.com/2018/06/29/people-hortavie-mpondo-une-actrice-qui-a-du-potentiel/. Retrieved 1 November 2020. 
  4. "Evénement : La mode streetwear en fête avec le DeidoBoy Fashion Day". Arthurhimins (in French). 23 March 2017. Archived from the original on 31 May 2019. Retrieved 1 November 2020. 
  5. Michele, Nougoum (6 October 2018). "INTERVIEW : THIERRY KAMDEM DÉNONCE LES VIOLENCES FAMILIALES DANS « ELLES », SON DERNIER FILM" (in French). Le Film Camerounais. https://lefilmcamerounais.com/2018/10/06/interview-thierry-kamdem-denonce-les-violences-familiales-dans-elles-son-dernier-film/. Retrieved 1 November 2020. 
  6. "Quelques actrices camerounaises à suivre !" (in French). Culturebene. 20 May 2019. http://www.culturebene.com/51176-quelques-actrices-camerounaises-a-suivre.html. Retrieved 1 November 2020. 
  7. Arlot, Alexandre (18 March 2019). "Meaux : le styliste aveugle a tourné « Coup de foudre à Yaoundé »" (in French). Le Parisien. https://www.leparisien.fr/seine-et-marne-77/meaux-le-styliste-aveugle-a-tourne-coup-de-foudre-a-yaounde-18-03-2019-8034279.php. Retrieved 1 November 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde àtúnṣe