Ibùdó Ogunléndé
Ibùdó Ogunléndé jẹ́ ibùdó pàjáwìrì tí wọ́n kọ́ láti pèsè ilé, àbọ̀, oúnjẹ, ìlera àti àwọn nǹkan mìíràn fún àwọn tí ó móríbọ́ ní agbègbè, ìlú tàbí orílẹ̀ èdè tí ogun ń jà tàbí tí wàhálà kan bẹ́ sílẹ̀ sí. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ó lè máà jẹ́ ogún, kí ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá pàjáwìrì bíi, ìjì búburú, iná, ìṣẹ̀lẹ̀ ẹṣin-ò-kọkú àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ìjàm̀bá búburú mìíràn ni wọ́n ṣe máa ń dá ibùdó Ogunléndé sílẹ̀.[1] [2]
Àwọn tí wọ́n máa ń dá Ibùdó Ogunléndé sílẹ̀
àtúnṣeÌjọba orílẹ̀ èdè, ìpínlẹ̀, ajo àgbáyé tàbí àjọ tó da orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè pọ̀, àjọ aṣèrànlọ́wọ́-ọ̀fẹ́ tí kìí ṣe ti ìjọba ló máa ń dá ibùdó Ogunléndé sílẹ̀ láti dá àbò bo àwọn tí ogún tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàm̀bá lé kúrò nílé tàbí orílẹ̀-èdè wọn.[3] [4]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "What is a Refugee Camp? Definition and Statistics". USA for UNHCR. Retrieved 2019-11-23.
- ↑ "Refugees". United Nations. 2015-12-14. Retrieved 2019-11-23.
- ↑ Commissioner, United Nations High. "Saving lives at the world's largest refugee camp". UNHCR. Retrieved 2019-11-23.
- ↑ "How to Build a Perfect Refugee Camp - The New York Times". Google. 2014-02-16. Retrieved 2019-11-23.