Idíófóònù
Idíófóònú ni ọ̀rọ̀ tí a fi máa ń ṣe àpèjúwe lọ́nà tí ó jẹ́ pé ìrísí tàbí ìtumọ̀ ohùn tí a ń ṣe àpèjúwe yóò yé ni dáadáa. Àwọn wọ̀nyí ni àbùdá Idíófóònú:
1. Idíófóònù gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kọ́ńsónáńtì.
2. Ìró ṣe pàtàkì nínú Idíófóònù yálà nípa fífarajọ ìró tí a ń ṣe àpèjúwe rẹ̀ tàbí nípa ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí a ń ṣe àpèjúwe.
3. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Idíófóònù ni a fi àpètúnpè ṣe ẹ̀dá wọn.
4. Idíófóònù kì í ṣe ìsòrí ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ nínú gírámà nítorí pé Idíófóònù lè jẹ́ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé, ọ̀rọ̀ àpèjúwe tàbí nígbà mìíràn ọ̀rọ̀ orúkọ. Bí àpẹẹrẹ:
* orí kọ̀bìtì - ọ̀rọ̀ àpèjúwe
* ó ń jà kìtìkìtì - ọ̀rọ̀ àpọ́nlé
* wọ́n ń ta wòsìwósì - ọ̀rọ̀ orúkọ
Oríṣi Idíófóònù
àtúnṣeOríṣi mẹ́ta ni Idíófóònù: firósínròójẹ, firómọ̀rísí àti àìfirómọ̀rísí.
Ídíófóònù Firósínròójẹ
àtúnṣeÓ jẹ́ èyí tí ìró Idíófóònù fara jọ ti nǹkan tí a ń ṣe àpèjúwe rẹ̀. Oríṣi mẹ́ta ni ìrísí Idíófóònù yìí.
A) Onísílébù kan tí ó ní kọ́ńsónáńtì àti fáwẹ́lì kan (KF)
Ó já bọ́ gbì
Ó ń ro tó
B) Onísílébù méjì tí ó ní kọ́ńsónáńtì kan àti fáwẹ́lì méjì (KFF)
Ó pupa fòò
Ó dá páú
D) Onísílébù méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú èyí tí kọ́ńsónáńtì tí ó ju ìkan wà
Ọbẹ̀ náà ń sọ ṣọ̀ṣọ̀
Idíófóònù Firómọ̀rísí
àtúnṣeIdíófóònù firómọ̀rísí ni èyí tí ìró Idíófóònù fara jọ ìrísí ohun tí a ń ṣe àpèjúwe rẹ̀. Oríṣi méjì ni irú Idíófóònù yìí.
A) Ìfarajọra dá lérí kọ́ńsónáńtì àti fáwẹ́lì - kọ̀ǹtì, gọ̀lọ̀tọ̀, wọrọkọ
B) Ìfarajọra dá lérí ohùn - játijàti, pálapàla, réú rèù
Idíófóònù Àìfirómọ̀rísí
àtúnṣeÀwọn Idíófóònù kan wà tí ìró wọn kò fi bẹ́ẹ̀ tọ́ka sí ìtumọ̀ wọn. Bí àpẹẹrẹ -
Ó dúró ṣinṣin
Ó dùn ṣinṣin
Ìṣẹ̀dá Idíófóònù
àtúnṣeÀpètúnpè ni a fi máa ń ṣẹ̀dá Idíófóònù, pàápàá àwọn Idíófóònù tí wọ́n ní ọ̀pọ̀ sílébù. Oríṣi méjì ni ó wà:
Idíófóònù oní-àpètúnpè kíkún
àtúnṣeOríṣi mẹ́ta ni èyí
A) Àpètúnpè sílébù ẹyọ kan - ọkan rẹ̀ ń dún ki ki ki
B) Àpètúnpè sílébù tí ó ju ẹyọ kan láìsí àyípadà ohùn - ṣàmùṣàmù, wàìwàì
D) Àpètúnpè sílébù tí ó ju ẹyọ kan pẹ̀lú àyípadà ohùn. Irú yìí máa ń fún Idíófóònù ni ìtumọ̀ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ - wérewère, pálá pàlà pálá
Ṣùgbọ́n kòbẹ́gbẹ́mu ni àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ wọ̀nyí nítorí pé àyípadà ohùn kò fún wọn ní ìtumọ̀ ọ̀tọ́: fùkùfúkù, wòsìwósì.
Idíófóònù oní-àpètúnpè ẹlẹ́bẹ
àtúnṣeApá kan irú Idíófóònù báyìí ni a máa ń ṣe àpètúnpè fún. Bí àpẹẹrẹ
* geere - geerege
* wọ́ọ́rọ́ - wọ́ọ́rọ́wọ́
Ìsọdorúkọ Idíófóònù
àtúnṣeỌ̀nà tí a fi ń ṣe ìsọdorúkọ láti ara Idíófóònù ni kí a fi àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ò/ọ̀ tàbí a kún Idíófóònù. Bí àpẹẹrẹ
* rara - ọ̀rara
* rinrin - ọ̀rinrin
* bọ̀rọ̀kọ̀tọ̀ - ọ̀bọ̀rọ̀kọ̀tọ̀
Ìfarajọra máa ń wà láàárín Idíófóònù àti àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ kan ṣùgbọ́n a ó lè ka àwọn eléyìí sí ìsọdorúkọ nítorí ìyàtọ̀ ìtumọ̀ tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín wọn. Bí àpẹẹrẹ
* ṣìgìdì (kí nnkan tóbi); ṣìgìdì (ère amọ̀)
* pàkìtì (kí nǹkan nípọn); pàkìtì (irú ẹni kan ti ó nípọn)