Idiat Ṣóbándé
Idiat Ṣóbándé jẹ́ gbajúmọ̀ Òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò èdè Yorùbá ọmọ Nàìjíríà. Wọ́n yàn án fún àmìn ẹ̀yẹ ti Òṣèrébìnrin tó dára jù ní ìpò olú-ẹ̀dá-ìtàn, Africa Movie Academy Award for Best Actress in a Leading Role lọ́dún 2011 fún ipa tí ó kó nínú sinimá àgbéléwò, Aramotu.
Idiat Ṣóbándé | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ìpínlẹ̀ Ògùn |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò |
Ìgbà iṣẹ́ | Ọdún 1995 sí àkókò yìí |
Gbajúmọ̀ fún | Aramotu |
Àwọn ọmọ | 2 |
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeIdiat jẹ́ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ tíátà lọ́dún 1995.[1] In 2011, Idiat revealed to Vanguard, that her role in Aramotu as a woman of affluence, prompted her to champion a case for gender equality in Nigeria.[2] Idiat ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá àgbéléwò èdè Yorùbá, lára wọn ni; Iyawo Sààráà, Àbọ̀dé Mecca, Kóńdó Ọlọ́pàá, Ọmọ Ìyá Àjọ and Aramotu.[2] Other notable films includes, Kondo Olopa (2007), Láròdá òjò (2008) and Ìgbẹ̀yìn Ewúro (2009).
Lọ́dún 2010, Idiat kópa olú ẹ̀dá ìtàn nínú sinimá Aramotu. Sinimá tó sọ nípa ipa pàtàkì tí àwọn obìnrin Yorùbá láwùjọ. Ipa yìí mú kí wọ́n yàn án fún àmìn-ẹ̀yẹ Òṣèrébìnrin tó dára jù ní ìpò olú-ẹ̀dá-ìtàn, Africa Movie Academy Award for Best Actress in a Leading Role, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò gbà á. Ó pàdánù àmì ẹ̀yẹ fún akẹgbẹ́ rẹ̀, Ama Abebrese [3][4]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Adebayo, Abimbola (2012-08-03). "Nigeria: I Do Not Lobby for Roles, Says AMAA Award Nominee, Shobande". allAfrica.com. Retrieved 2017-11-20.
- ↑ 2.0 2.1 "Idiat Sobande of Aramotu fame may remarry". vanguardngr.com. 2011-12-31. Retrieved 2017-11-20.
- ↑ "How Aramotu was born". nigeriafilms.com. Retrieved 2017-11-20.
- ↑ "AMAA reveals 2011 nominations list". thenet.ng. 2011-02-26. Retrieved 2017-11-20.