Ifẹ̀wàrà

(Àtúnjúwe láti Ifewara)

Ìfẹ̀wàrà jẹ́ ìlú kékeré kan ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni Nàìjíríà Gẹ́gẹ́ bí a sọ ṣaájú, ìwádìí lórí iṣẹ́ yìí dé Ìjọba Ìbílẹ̀ Àtàkúmọ̀sà tí ó ní ibùjókòó rẹ̀ ní Òṣú. Ní ìjọba ìbìlẹ̀ yìí, gbogbo àwọn ìlú àti abúlèko tí ó wà ní ibẹ̀ ló jẹ́ ti Ìjẹ̀ṣà. Ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀ṣà ni wọ́n sì ń sọ àfi Ifẹ̀wàrà tí ó jẹ́ ẹ̀yà ẹ̀kà-èdè Ifẹ̀ ni wọ́n ń sọ. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn tí gbọ́, Ifẹ̀ ni àwọn ará Ifẹ̀wàrà ti ṣí lọ sí ìlú náà láti agboolé Arùbíìdì ní òkè Mọ̀rìṣà ní Ilé-Ifẹ̀1 . Ìwádìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ oyè ló dá ìjà sílẹ̀ ní ààrin tẹ̀gbọ́ntàbúrò. Ẹ̀gbọ́n fẹ́ jẹ oyè, àbúrò náà sì ń fẹ́ jẹ oyè náà. Ọ̀rọ̀ yìí dá yánpọn-yánrin sílẹ̀ ní ààrin wọn. Lórí ìjà oyè yìí ni wọ́n w`atí ẹ̀gbọ́n fi lọ sí oko. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀gbọ́n tó ti oko dé, ipè láti jẹ oyè dún. Àbúrò tí ó wà ní ilé ní àsìkò náà ló jẹ́

1. Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú arábìnrin Julianah aya ni 17/6/92.

2. Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú Olóyè Fákówàjọ ni 17/6/92. Ipé náà. Ipè ti sé ẹ̀gbọ́n mọ́ oko. Èyí bí ẹ̀gbọ́n nínú nígbà tí ó gbọ́ pé àbúrò òun ti jẹ òyé, ó sì kọ̀ láti padà wá sí ilé nítorí pé kò lè fi orí balẹ̀ fún àbúrò rẹ̀ tí ó ti jẹ oyè. Ọ̀rọ̀ yìí di ohun tí wọn ń gbé ogun ja ara wọn sí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Nígbà tí ẹ̀gbọ́n yìí wá ń gbé ogun ja àbúrò rẹ̀ ní Ifẹ̀ lemọ́lemọ́, ni àwọn Ifẹ̀ bá fi ẹ̀pà ṣe oògùn sí ẹnu odi ìlú ní Ìlódè. Wọ́n sì fi màrìwò ṣe àmì sì ọ̀gangan ibi tí wọ́n ṣe oògùn náà sí. Láti ìgbà yìí ni ogun ẹ̀gbọ́n kò ti lè wọ Ifẹ̀ mọ. Àwọn Ìjẹ̀ṣà ní ó ni kí ẹ̀gbọ́n tí ó ń bínú yìí lọ tẹ̀dó sí Ìwàrà. Nígbà tí wọ́n dé Ìwàrà, wọ́n fi mọ̀rìwò ọ̀pẹ gún ilẹ̀, kí ilẹ̀ tó mọ́ mọ̀rìwò kọ̀ọ̀kan ti di igi ọ̀pẹ kọ̀ọ̀kan.Ìṣẹ̀lẹ̀ tẹ̀lẹ̀, wọ́n sì pinnu pé àwọn kò níí lè bá àwọn àlejò náà gbé nítorí pé olóògùn ni wọn. Èyí ló mú kí àwọn ara Ìwàrà lé àwọn àlejò náà sí iwájú. Ibi tí àwọn àlejò náà tẹ̀dó sí lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Ìwàrà ni a mọ̀ sí Ifẹ̀wàrà lónìí. Lóòótọ́ orí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni Ifẹ̀wàrà wà ṣùgbọ́n kò sí àjọṣepọ̀ kan dàbí alárà láàrin Ifẹ̀wàrà, Iléṣà àti Ìwàrà títí di òní pàápàá nípa ẹ̀ka-èdè tí wọn ń sọ.

Àkíyèsí fi hàn pé gbogbo orúkọ àdúgbò tí ó wà ní Ifẹ̀ náà ni ó wà ní Ifẹ̀wàrà. A rí agboolé bí Arùbíìdì, Mọ̀ọ̀rẹ̀, Òkèrèwè, Lókòrẹ́ àti Èyindi ní Ifẹ̀wàrà.

Bákan náà ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ nì wọ́n ń sọ ní Ifẹ̀wàrà. Àsìkò tí wọ́n bá sì ń ṣe ọdún ìbílẹ̀ ní Ifẹ̀ náà ni àwọn ará Ifẹ̀wàrà máa ń ṣe tiwọn.

Ìwádìí nípa ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ìlú tí iṣẹ́ yìí dé fi hàn gbangba pé mọ̀lẹ́bí ni Ifẹ̀, Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó pẹ̀lú Òkè-Igbo, àti Ifẹ̀wàrà. Wọ́n jọra nínú ìṣesí wọn. Ẹ̀ka-èdè wọn dọ́gba, orúkọ àdúgbò wọn tún bára mu, bákan náà ni ẹ̀sìn wọn tún dọ́gba. Àkókó tí wọ́n ń ṣe ọdún ìbílẹ̀ kò yàtọ̀ sí ara wọn. Bí ẹrú bá sì jọra, ó dájú pé ilé kan náà ni wọ́n ti jáde.

  • Ifèwàrà, C.O. Odéjobí DALL, OAU, Ifè, Nigeria