Ààlọ́ ooooo

Ààlọ [1]

Ààlọ́ mi dá lórí Ìjàpá àti Ìgbín.

Ní Ìgbà láéláé , Ìjàpá fẹ́ ọmọbìnrin

kan lọ́wọ́ ìgbín . Akíkanjú ni Ìgbín jẹ́ nínú isẹ oko dídá, ó sì dá oko isu ńlá sí ọ̀nà ojà ìlú . Olè kan wà ó má ń jí isu náà wà ní gbogbo ìgbà ṣùgbọ́n ìgbín kò sì mo irú ènìyàn tó ń se irú isẹ bẹ́ẹ̀ . Ìjàpá pàápàá ń bá ìgbín kẹ́dùn nípa isu náà , bẹ́ẹ̀ ni òun gangan ni ó ń jí ìṣù náà wà lo.

Ṣùgbọ́n fèrè tí ilè ọjọ́ kan mọ .Bí ìgbín ti yọ kéléké lé dé inú oko rẹ .Ìjàpá ni ó bá nínú oko rẹ tí ń jí isu wà. inú sì bí ìgbín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ gan nítorípé Ìjàpá tí ó ń ba kẹ́dùn gan ni ó ń jí isu rẹ wà .Ẹnu ya ìgbín púpò pé Ìjàpá tí òun fún ní ọmọ tún lè máa wu irú ìwà bẹ́ẹ̀ sí òun .Ó rántí bí Ìjàpá ti máa bá òun kẹ́dùn lórí olè tí ó máa jí isu òun wà. Ó sì pinnu pé òun yóò fi Ìjàpá se ẹlẹ́yà dé ààyè kan.Ọjọ́ ojà ni ọjọ́ náà jẹ, nítorí náà ,ìgbín de Ìjàpá mọ́lẹ̀ sí ojú ọ̀nà ,gbogbo àwọn èrò tí ó ń lọ ọjà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi se ẹlẹ́yà .Wọ́n ń sọ pé 'Họ́wù ! Ìwọ Ìjàpá aláìnítìjú yìí ! Eni tí ó fún ọ lọmọ ni o sì tún lọ jí ní isu wà. Si ọ , Ọlọ́ṣà  ! Ìjàpá dá ké , ko wí nǹkan kan títí wón èrò ọjà fi kọjá tán.Lẹ́yìn ó sií bẹ ìgbín .Ó wá bí ìgbín pé ,gbó mi ná o; Ó wá tó gee báyìí o; jọ̀wọ́ tú mi sílè o.Lotiito mo ti se ohun tí kò dára , mo sì jèrè gbogbo èébú tí àwọn èrò ọjà ti ń búmi; ṣùgbọ́n yóò burú kí wọn tún bá mi báyìí ní àbọ̀ ọjà o.Nítorí náà ,jọ̀wọ́ tú mi sílè Ọlọ́run ! Ṣùgbọ́n ìgbín kò fẹ́ Ìjàpá sílè ;O fẹ́ kí àwọn èrò ọjà tún bú u ní àbọ̀ ọjà .Láìpé lọ títí ,àwọn èrò ojà bẹ̀rẹ̀ si í padà dé ,wọ́n sì tún bá Ìjàpá lórí ìdè níbi tí ó ń ṣẹ ojú mi péú .Ẹnu yà wọn púpọ̀ ,wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bú ìgbín báyìí Họ́wù , ìgbín , o fẹ́ pa á ni? Òtòkí _ tokì pé o jẹ àna rẹ nìyí ! Ṣe bí òun pẹ̀lú ọmọ rẹ ni wọn jọ ń jẹ isu náà ! Èyí mà le o! Bí kò bá jẹ́ àna rẹ ńkọ́ ,se pípa ni ò bá pá á, ojú ti ìgbín púpò, nígbà tí gbogbo wón ń bú ìgbín ní àbúgbà báyìí , ó sì tú Ìjàpá sí ilẹ. Nígbà náà ni Ìjàpá wá bẹ̀rẹ̀ si i fi ìgbín se ẹlẹ́yà.Ó ní ,'kò tán ní ìdí rẹ. Ìwọ ìgbín ! O bá ti tú mi sílẹ̀ nígbà tí mo tí bẹ ọ , ìbá yẹ ọ titi . Àṣejù rẹ ni ó jẹ kí o tẹ yìí .Èyí ni àwọn àgbàlagbà se máa ń pa á lowe pé ,'Èébú àlọ ni ti Ahun , t'àbò ni ti àna rẹ ;[2]

Ẹ̀KỌ́ INÚ ÀÀLÓ

àtúnṣe

Ìwà àṣejù kò dára o.

ÀWỌN ÌTỌ́KASÍ

àtúnṣe
  1. https://yorubafolktales.wordpress.com/
  2. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales