Ijeoma Grace Agu jẹ́ òṣèré ọmọ Nàìjíríà kan. Ó jẹ ànfàní yíyàn fún òṣèré lóbìnrin tí ó dára jùlọ ní ipa àtìlẹyìn ní bi 12th Africa Movie Academy Awards. Ó tún gba ẹ̀bun òṣèré tí ó ní ìlérí jùlọ ní bi 2014 Best of Nollywood Awards. Ní ọdún 2007, ó ṣe ìfihàn àkọ́kọ́ rẹ̀ lójú amóhù-máwòran nínu eré tẹlifíṣónù Eldorado. Ó tún jẹ́ òkan lára àwọn ẹgbẹ́ àṣà ńi ti 2012 London Olympic Games.[1][2]

Ijeoma Grace Agu
Ọjọ́ìbíIjeoma Grace Agu
16 Osu Kefa
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Ẹ̀kọ́Nnamdi Azikiwe University
Iṣẹ́Osere
Notable workJust Not Married

Ìgbésí ayé rẹ̀

àtúnṣe

Agu ni àkọ́kọ́ nínu àwọn ọmọ márùn-ún ti òbí rẹ̀. Gẹ́gẹ́bí ìjábọ̀ ti Pulse Nigeria, Agu dàgbà ní Ìlu Benin àti Ìpínlẹ̀ Èkó.[3] Ó ní oyè-ẹ̀kọ́ nínu Biochemistry láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Nnamdi Azikiwe ní ọdún 2007. Ó ti ní ọkọ pẹ̀lú ọmọbìnrin kan.[4] Ó tọ́kasí bàba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ẹni tó fun ní ìgboyà láti ṣe iṣẹ́ eré ìtàgé.[1] Gẹ́gẹ́bí Agu ṣe sọ, iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní orí ìpele ní Benin ní ọmọ ọdún 14.[1] Nígbàtí ó n sọ̀rọ̀ sí The Nation (Nigeria) lóri ìbálòpọ̀ ẹlẹ́yà kan náà ní Nollywood, Agu ṣàpèjúwe ìṣe náà bi ẹ̀ṣẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀sìn àti pé kò rò pé òfin rẹ̀ jẹ́ ìrúfin àwọn ẹ̀tọ́ ènìyàn. Síbẹ̀síbẹ̀, ó sọ àsọyé pé kò yẹ kí wọ́n ri bí ìwà ọ̀daràn bí ó ti ń ṣe ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà. Ó tún ṣàlàyé pé òun kò ṣe àtìlẹyìn ohunkóhun tí yóó já sí ìpàdánù ẹ̀mí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, nígbà t́i wọ́n bií léèrè nípa ìtara fún Biafra.

Àkójọ eré rẹ̀

àtúnṣe
  • The Arrangement
  • Beyond Blood
  • One Room
  • The Choice of Aina
  • Flower Girl
  • From Within
  • Just Not Married
  • Kpians: The Feast of Souls (2014)
  • Taxi Driver
  • Hoodrush
  • Misfits
  • Love In A Time of Kekes
  • Women Are Scum
  • Package deal
  • Sylvia


Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 "I CAN ACT NUDE–IJEOMA GRACE AGU". thenationonlineng.net. Retrieved 26 July 2016. 
  2. "Nollywood Actress Ijeoma Grace Agu gets Risqué in New Photos". bellanaija.com. Retrieved 26 July 2016. 
  3. "10 things you should know about "Taxi Driver: Oko Ashewo" actress". pulse.ng. Archived from the original on 13 February 2020. Retrieved 26 July 2016. 
  4. "Ijeoma Grace Agu Speaks On Acting Career". topcelebritiesng.com. Archived from the original on 10 May 2017. Retrieved 26 July 2016.