Ilé-Ìkàwé orílẹ̀ èdè Gambia
Ilé ìkàwé orílẹ̀ èdè Gambia jẹ́ ilé ìkàwé àgbà ti orílẹ̀ èdè Gambia, ó wà ní Banjul, olú Ìpínlẹ̀ Gambia.[1] Ilé ìkàwé náà wá lábẹ́ ìjọba British títí di ọdún 1946 wọ́n sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí National Library of The Gambia ní ọdún 1971. Ó wà ní abé ìdarí Gambia National Library Services Authority (GNLSA). Àkọsílẹ̀ ọdún 2016 fi hàn pé ilé ìkàwé náà ní tó ìwé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàta lé ní ọ̀kẹ́ màrún àbọ̀ (115,500). Ó sì ní òṣìṣẹ́ tí ó lé ní méjìlélógójì.
Ìtàn
àtúnṣeIlé ìkàwé náà wà lábẹ́ ìdarí orílẹ̀ èdè British títí di ọdún 1946. Sally Njie di adarí àgbà ilé ìkàwé náà ní ọdún 1963.[2] Ìjọba British fún Gambia ní owó tí ó £575,000 fún àtúnṣe àti ìtọ́jú ilé ìkàwé náà ní ọdún 1974. Wọ́n kọ́ ilé ìkàwé míràn wọ́n sì kó àwọn ìwé lọ ibẹ̀ ní ọdún 1976.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ List of Addresses of the Major Libraries in Africa (Archived 30 June 2012 at the Wayback Machine.)
- ↑ Mary A. Thornhill, Factors in library development in The Gambia, Master's Thesis, Loughborough University, 1983, p.80, 89, 131.