Ilé-iṣẹ́ Senegal, tí kíkọ rẹ̀ ní èdè Faranse jẹ́ Compagnie du Sénégal jẹ́ ilé-iṣẹ́ sẹ́ńtútì kẹtàdínológún ti ìlú Faranse tó ń rí sí ìṣe àwọn agbègbè bí i Saint-Louis àti Gorée island tó jẹ́ apá kan ilẹ̀ Faranse ti Senegal.

Máàpù "Barbaria, Nigritia, àti Guinea" ní Guillaume de l'Isle.ti ọdún 1707

Ilé-iṣẹ́ àkọ́kọ́

àtúnṣe

Ilé-iṣẹ́ náà gbilẹ̀ sí àwọn agbègbè kan ní French West India Company, ní ọdún 1672, ìyẹn lẹ́yìn ìwọgbèsè wọn àti fífagilé ìwé-àdéhùn rẹ̀ ní ọdún 1674. Sieur de Richemont sìn gẹ́gẹ́ bí i Gómínà agbègbè náà, láti ọdún 1672 wọ ọdún 1673, ti Jacques Fuméchon, sì jẹ́ olùdarí lẹ́yìn rẹ̀, tó sìn títí wọ ọdún1682. Compagnie royale d'Afrique àti Compagnie de Guinea gba ìṣàkóso ètò ọrọ̀-ajé ilé-iṣẹ́ náà.

Ilé-iṣẹ́ kejì

àtúnṣe

Ní ọdún 1696, wọ́n ṣèdásílẹ̀ Compagnie royale du Sénégal, Jean Bourguignon sì jẹ́ alákòóso rẹ̀ láti oṣù kẹta ọdún 1696 wọ oṣù kẹrin ọdún 1697, léyìn náà ni André Brue gbàjọba, ó sì ṣàkóso títí wọ ọdún oṣù karùn-ún ọdún 1702. Wọ́n ṣe òwò ẹrú pẹ̀lú àwọn ará Hausa, ní Mali, àti Mauritania.

Ilé-iṣẹ́ kẹta

àtúnṣe

Ní ọdún 1709, wọ́n ṣèdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Compagnie du Sénégal, ẹlẹ́ẹ̀kẹta.

Àwọn ìọ́kasí

àtúnṣe