Ìlaró jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú ní ìpínlẹ̀ Ògùn, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí àwọn ènìyàn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rin àti àádọ́ta. Ìlaró[1] jẹ́ ìlú tí ilé ìjọba ìbílẹ̀ tí ó ṣàkóso gbogbo gúúsù Yewa wà, tí a mọ̀ sí Yewaland. Àádọ́ta kìlómítà ní Ilaro fi jìnnà sí ìlú Abẹ́òkúta, níbití olú-ìlú ìpínlè Ògùn wà.

A statue of Orona, a great warrior of ancient times, in the town

Ìlú yìí súnmọ ibi tí wọ́n kọ́ gbọ̀ngàn Orona, tí wọ́n kọ́ ní ìráńtí ológun náà.

Osata jẹ́ olórí àtijọ́ ní ìlú Ilaro ní sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún, tó fi ọmọ rẹ̀ rúbọ kí àwọn ènìyàn ba lè gbádùn òjò lásìkò tí ìyàn mú ní ìlú náà.[2] Ẹ̀ka èdè tí wọ́n ń sọ ní ìlú yìí ni Ẹ̀gbádò. Tí àwọn ọmọ Ilaro bá pàdé níta, wọ́n máa kígbe pé “Omo Oluwewun” ní agbára láti sọ "Ilu Aro" pọ̀.

Iṣẹ́ àgbẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ ajé

àtúnṣe

Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn Yewa/Egbado mú lókùn-ún kún dùn tẹ́lẹ̀, àwọn ohun ọ̀gbìn wọn sì ni kòkó, kọfí, obì, ọsàn, àti pineapple. Àwọn ohun ọ̀gbìn mìíràn ni ẹ̀gẹ́, iṣu, ilá, ìrẹsì, ọ̀gẹ̀dẹ̀ jíjẹ, ọ̀gẹ̀dẹ̀ dídín, gúre, àti efinrin. Àwọn ohun àlùmọ́nì ìlú Ilaro ni Phosphate àti limestone. Ilẹ̀ Ilaro dára fún iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì máa ń jẹ́ kí àwọn ohun ọ̀gbìn bí i kòkó, kaṣú, ìbẹ́pẹ, àgbàdo, ìrèké àti ọ̀dùnkún tètè hù dáadáa.

Látàkí àwon igbó kìjikìji ní ìlú yìí, iṣẹ́ gẹdú náà tún wà lára àwon iṣẹ́ tí wọ́n yàn láàyò ní ìlú Ilaro. Oríṣiríṣi ilé-iṣẹ́ agégi gẹdú ni ó wà níbẹ̀, tí wọ́n ti ń ṣe pákó, tí wọ́n sì ń tà á.

Lára àwọn ilé-iṣẹ́ ìmíì ní Ilaro ni ilé-iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe fùfú àti gàrí, ilé-iṣẹ́ agégi gẹdú, àwọn aláṣọ òkè, ilé-iṣé tó ń ṣe ọ̀dà àti sìmẹ́ǹtì.

Ìṣèlú

àtúnṣe

Ilé-ẹjọ́ gíga àti ilé-ẹjọ́ màjísíréètì wà ní ìlú náà.

Ojú ọjọ́

àtúnṣe

Ìwọ̀n ojú-ọjọ́ ní Ilaro máa ń jẹ́ 23 °C sí 34.2 °C.

Ètò-ẹ̀kọ́

àtúnṣe

Ilaro ní ilé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, ilé-ìwé girama, àti ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Lára àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga tó wà níbẹ̀ ni Egbado Teachers Training College, Ilaro, àti Federal Polytechnic Ilaro, èyí tí wọ́n dá sílẹl ní September, ọdún 1979. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ aládàáni ló wà káàkiri ìlú náà. Ilaro tún ní Polytechnic Staff Primary and Secondary schools.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Ilaro." Encyclopædia Britannica. Encyclopædia Britannica Online. Encyclopædia Britannica, 2011. Web. 29 Mar. 2011. [1].
  2. Oral story of Ilaro town as told by Pa James Aderounmu Oniyide, of Iga Ekerin Compound, Ilaro Ogun State, Nigeria