Ilé-Ifẹ̀

(Àtúnjúwe láti Ile-Ife)

Ilé-Ifẹ̀ jẹ́ ìlú ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Naijiria.

Ilé-Ifẹ̀
Ìlú

Orin ìwúrí é-Ifẹ̀Àtúnṣe

 1. Ilé Ifẹ̀, Ifẹ̀ẹ tèmi
 2. Ilé Ifẹ̀, ìlú àwọn akọni
 3. Ibùgbé àwọn ènìyàn jàǹkàn
 4. Ibi ìfiṣolẹ̀ oríi Yoòbá
 5. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí mo purọ́, ẹ sọ́ 5
 6. Ibẹ̀ nilé Àdìmúlà Ọọ̀ni Ifẹ̀
 7. Àjàláyé Ọlọ́fin Oòduà
 8. Ọ̀rànmíyàn ọba aláyé lu jára
 9. Mọrẹ̀mi òǹgbà tíí gbará àdúgbò
 10. Ẹ̀là Ìwòrì, ikọ̀ àjàlọ́run 10
 11. Òrìṣà bàmùtàtà bàmùtata tá a fi rọ́mọ ẹ̀dá padà
 12. Ilé Ifẹ̀, ìlú àwọn olùdá ayé
 13. Ifẹ̀, ìlụ́ àwọn àtọ̀runbọ̀
 14. Ifẹ̀ ni wọ́n gbé gbolúbi dúdú, funfun
 15. Ìyín lèèyàn òòṣà pàápàá forí rìn dé 15
 16. Njẹ́ ìwọ Ifẹ̀ oòyè dabọ̀, olórí ayé gbogbo
 17. Mo rántí bíyàà mi àgbà ṣe mọ́-ọn ń fi ọ́ kọrin
 18. Létí odò ẹ̀sìnmìrìn
 19. N kò rí ọ rí ká sọ pàtó
 20. Ṣùgbọ́n mo ríyà tó o jẹ lóríi wa 20
 21. Ojúù mi kò ṣàìtéjẹ̀ẹ̀ rẹ
 22. Ẹ̀jẹ̀ tó o ta sílẹ̀ fún wa
 23. Ẹ̀jẹ̀ tó tọwọ́ ìyà wá
 24. Ìyà tó tọwọ́ ìṣẹ́ wá
 25. Ìṣẹ́ tó tọwọ́ ẹ̀gbin rọ̀ọ́lẹ̀ 25
 26. Nígbà tọ́mọ tá a bí dé
 27. Wáá fọwọ́ ọrọ̀ júweelée baba ẹ̀
 28. Tí funfun dé wáá kó ọ lẹ́rú
 29. Tó kó ẹ tọmọ tòòṣà
 30. Ọ̀gọ̀rọ̀ òòṣàa wa la fi ṣàfẹ́ẹ̀rí 30
 31. Tá a firúnmọlẹ̀ ṣàwátì
 32. Òsùpá Ìjió ti lọ tèfètèfè
 33. Ilé-Ifẹ̀, ǹjẹ́ sọ fún mi, Ifẹ̀ oòyè dabọ̀
 34. Ṣ̣éwọ náà làwọn alára bátabàta ṣe báyìí ṣe?
 35. Tí wọ́n dójú tì ọ́, tí wọ́n kẹ́gbin bá
 36. ọ láa 35
 37. Ǹjẹ́ kí la ó ti sọ̀rọ̀ọ̀ wọn sí, ìwọ Ifẹ̀?
 38. Ká sáà fi wọ́n sílẹ̀ máa wòye
 39. Ká fọ̀rọ̀ fúnrúnmọlẹ̀
 40. Ká fáwọn igbámọlẹ̀ lọ́rọ̀ sọ
 41. Ká fọ̀rọ̀ ṣẹbọ ká fi ṣètùtù 40
 42. Kóhun rere tún lè padà sílé ifẹ̀
 43. Ení bá ní kẹ́bọ má dà
 44. Kó máa bẹ́bọ lọ réré ayé.


Coordinates: 7°28′N 4°34′E / 7.467°N 4.567°E / 7.467; 4.567