Ìlú ẹ̀yọ

(Àtúnjúwe láti Ilu eyo)

Ilu eyo kiki Egba


Ìlú ẹ̀yọ kìkì Ẹ̀gbà

àtúnṣe

Oorun!

Oorun!!

Oorun!!! Oorun ti ń gba tọwọ́ ọmọdé.

Tọwọ́ ọmọdé nìkan ló ha ń gbà nì? N ò mọ ìgbà tí oorun tún rá mi lọ pàfe. Mo wá tẹ́ra sílẹ̀ bí àtẹ ọ̀rúnlá tàbí bí obìnrin tí ń sàníyàn ọkọ. Mo nawọ́ mú oorun yìí lójú páálí. Àlá àkọ́kọ́ ni mo rí tí mò ń wí, gbankọgbì nit i ìkejì tí n ó ròyin rẹ̀ fún yín yìí....

Bo ba tasiko


Bó ba tó Àsìkò Àtisu, Fúrọ̀ níláti lá

àtúnṣe

Bàbá Amòye wò mi. Ó fẹ̀rín sí. Bàbá Amòye tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ pé: Méjì là á wònìyàn; Bí ò jẹ́ ti yínyìn, a jẹ́ ti èébú. Gbogbo ẹyẹ kọ́ ló sì ṣe ń sùn lálẹ́. Gbogbo ìgbà tí ẹ̀nìyàn bá wọsọ olúmẹ̀yẹ kọ́ laráyé máa ń fẹ́ kọ́ yẹni. Àrokò ńlá ni ọmọ tó bẹ́tọ́ sí ọ lára pa fún ọ ti o ò mọ̀. Kò mọ̀ ṣéni tó le ríre tí ò ni ribi gín-ń-ginní rẹ̀ tọ̀ ọ́....

Ifa o si lodo Oba

Odo Oba

Ìfà Ò sí lódò Ọbà

àtúnṣe

Tàánú-tàánu tí ológbò ń rìn sọdẹ eku ni à ń rìn ni Ìkọ̀lé ọ̀run. Èmi àti baba Amòye la jẹun tán, mo yó. Mo yó, mo ṣekùn wọnle; mo yó, mo ṣekùn bọnbọ. Mo fi ọkàn balẹ̀ jẹun ọ̀ún ni. Baba wọlé jáde. Jíjáde rẹ̀ yìí bà mi lẹ́ru gan-an ni. Ara mi ń sú gàn-in gàn-ìn. Ẹ̀rù sì ń yọ́ mi bà láìjẹ gbèṣè....

Iwoyi Ijebu, mo ti tanaa de

Ìwòyí ìjẹ̀bú mo ti tàná dé

àtúnṣe

Ìwòyí Ìjẹ̀bú, mo ti tàná dé. Èpè kọ́, n ó máa nà án lẹ́fọ̀ ni. A lọ́mọdé ò mẹ̀là. Ó lóun mẹ̀làkátakàta. Bẹ́ẹ̀ ẹ̀lá kátakàta ni baba ẹ̀là. Dákun máà saájú mọ - risà o. Bí a bá ti ń pọn Mọ́gbè. Kò yẹ kí Mọ́gbè tún máa pọngbá. Bí o wà níbí di ẹgbẹ̀rún ọdún, a ò ni fi ìkan pe méjì fún ọ. Kí o wá padà si Ìkọ̀lé ayé. Ó tó gẹ́ẹ̀, aludùndún kì í dárin. ...

Ikole orun

Heaven

Ìkọ̀lé Ọrun

àtúnṣe

Fọ̀rànsínú lajá mi ń jẹ́; N ò n fi ọ̀rọ̀ eléyìí sinú. Tẹnumọ́ràn ni mo sọ ẹran mi. Ibi ọ̀rọ̀ ni mo wà; N ò tí ì lọ.

Ayé ní kọ̀rọ̀.

Kí Ọlọ́run má fi wá sí kọ̀rọ̀ ayé, ọ̀run náà mọ̀ ni kọ̀rọ̀; Bẹ́ẹ̀-kí-í-ṣe, a à ní bá bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀; Bẹ́ẹ̀-ni-i-ṣe ò sin í í fi bẹ́ẹ̀ sílẹ̀. Àtire àtìkà wa nìyí kò sí ọ̀ken tó gbé; A ó jèrè rẹ̀ láyé níbí. ...

Arẹwà tó rẹwà Mẹ́wà

àtúnṣe

Ó na mọ́lúbí àkọ́kọ́ si mi. Mo ranjú kankan mọ́ mọ́lúbi Ọ̀nà riri lẹ̀gbọ́n; Agbára làbúrò ènìyàn le lagbára kó máà rí ọ̀nà. Ọkùnrin Arẹwà ti mo ri lójú mọ́lúbi yìí rẹwà; ẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀ẹ̀. Kò sẹ́ni tỌ́lọ́run ó ṣe fún; ó ṣe fájá; ó ṣe fẹ́ran; Ó ṣe fún kùkùté ẹ̀bá ọ̀nà; ó ṣe fún akúwárápá ó ń janra rẹ̀ mọ́lẹ̀. ...

Ìpín-ún lẹ̀dá ba Gbáyè

àtúnṣe

Baba tún fa mọ́lúbi mìíràn yọ. N óò sọ ohun tí mo rí nibẹ̀ fún ọ. Mo ranjú kankan kan mọ́ jígí . àwò-àìṣẹ́jú; Àwòyanusílẹ̀; Awòsílẹ̀kùn èrò. Oríṣìíríṣìí èrò ló ń gba ọkàn mi bí mo ti ń wo jígí yìí lọ. Ìgbà mìíràn màá dájọ́. Ìgbà mìíràn màà pòṣé sààràsà; ìgbà mìíràn màá tú yẹ̀rì ètè; màá tújú ká. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo sì ń yanu tán rẹ́rìn-ín. ...

Abúlé Ẹ̀san

àtúnṣe

Ẹni ti oríyà rí ni kó gbá àbúlé Ẹ̀san lọ. Kó yà ni apá ọ̀tún ní òpópó ìjìyà ẹ̀sẹ̀. Tó bá dé ibẹ̀, yóò ṣe ìdárò fálábiamọ. Ibi ti àwọn kan ti ń gbá adùn ní ikọ̀lé ọ̀run ni a tún ti rí àwọn kan tí ń gbá ìyà. Ibi tí àwọn kan ti ń gbá owó ni àwọn kan ti ǹ gbá òsi. ..

Àlá ni mò á la

àtúnṣe

Bí wọn tí ń ṣe láyé náà ni wọn ń ṣe lọ́run. Ẹ̀rín ò yàtọ̀ tó fi délùú Òyìnbó. Wọ́n ń sún láyé; wọ́n ń sùn lọ́run. Wọ́n ń gbádùn láyé; wọn ń gbádùn lọ́run. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ tí mò tí rí kọ́ nÍkọ̀lé ọ̀run, oorun rá mi lọ lọ́wọ́ kan ni sáá. Mo wá ń fa oorun ọ̀ún fin-ìn bi igbà tí ẹ̀fọn bá mùjẹ̀. ...

S.M. Raji (2001), Ìkọ̀lé Ọ̀run Alafas Nigeria Company Ibadan. ISBN 978 32525 02, oju-iwe 1-73.

S.M. Raji

link title Archived 2007-08-07 at the Wayback Machine.