Ilu ti nkorin
Ààló Ìjàpá àti Atilọ́lá
Ààlọ́ oooo[1]
Ààlọ
Ààlo mi dá firigbagbo, ó dá lórí Ìjàpá àti ọmọdékùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atilọ́lá.
Ní ìgbà kan, ọmọdékùnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àtilọ́lá . Àwọn òbí rè fẹ́ràn rẹ gidigidi nítorípé òun nìkan ni wọn ní . Wọn kò sì fi ohunkóhun dùú; se ni wọn máa ńṣe ní ohun ẹlẹgẹ; wọn ki í fẹ́ kí ẹnikẹ́ni bá a wí bí ó tilẹ̀ hùwà tó burú . Nítorí ìdí èyí Atilọ́lá máa ńṣe ise ọmọ oníbàjẹ́ , ki í sì gbọ́ràn sí ẹnikẹ́ni lẹ́nu . Ní ọjọ́ kan ní ìgbà àárọ̀ ọjọ́ , Atilọlá ní òun fẹ́ lọ ṣeré pẹ̀lú àwọn ọrẹ òun ní ojúde , ìyá rẹ sọ wipe kó má ṣe jínijìni lọ síbè . Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ , Atilọlá kọ tí ikùn sí àmọràn ìyá rẹ ó sì wá àwọn ọrẹ rẹ lọ . Nígbà tí ó dé ọdọ àwọn ọrẹ rẹ , ó ṣeré lọ sí àfonífojì láti lọ wá oyin. Ṣùgbọ́n bí ó se wo àfonífojì ni wọn rí pé ojo ti sú ní ojú ọ̀run , ààrá sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣán, ‘paa’. Ọ̀kan nínú àwọn ọrẹ Atilọlá dábàá wípé káwọn padà lọ sílé kí òjò tó bẹ̀rẹ̀ sí i rọ̀ . Àwọn èèyàn ri í pé àbá yìí dára , wọn sì múra láti padà, ṣùgbọ́n Atilọlá sọ pé , ‘Èmi o ní padà ní tèmi o, oyin ni mo wá débí èmi ò sì ní kúrò níbí láì róyin’.
‘Báwo là se fẹ rí oyin nínú ojo yìí?’ Ọkan nínú àwọn ọrẹ rẹ bèèrè . B’emi o bá le rí oyin nínú omi, emi o dúró tójo yoo fi dá . Bí Atilọlá ti parí ọ̀rọ̀ rẹ ni ojo bẹ̀rẹ̀ sí fọ́n . …wọn padà sí abúlé won sì fi òun nìkan sílè kó máa wá oyin. Láìpé , ojo bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ , ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di adágún omi kékeré .
Atilọlá nfò síhìn-ín n sọ́hùn-ún bí alágemọ , ó njuwọ́ sókè , sílè ó sì ń fowó gbe omi. Àwọn àgbè tó ń padà lọ sile látinú oko sọ fún pé kí ó kúrò nínú ojo kí ó máa lọ sínú abúlé . Ṣùgbọ́n nise ni ọmọ aláìgbọràn yìí fẹ ojú mọ wọn , ó ń yọ ahọ́n sí wọn , ó sì ń fi wọ́n se yẹyẹ́ , ó sì ń jó nínú adágún omi bí ojo ti ń rò sìi .[2]
L àìpé àgbàrá ojo gba gbogbo àfonífojì, Atilọlá kò sì rí ibi tí ó le sasi, ó rí igi odán kan tí ó lọ sí abẹ rẹ . Ṣùgbọ́n bí ojo yìí ti ń posi, Atilọlá pinnu láti gun igi lọ kí agbára ojo má ba a gbe e lọ . Ní kété tí ó fe máa gùn igi yìí ni ó kọsẹ tí ó sì ṣubú sínú àgbàrá tí omi sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé e lọ . Atilọlá fi igbe ta, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì tó wà nítòsí . Bí omi se ń gbé e lọ , ó rí àwọn igi weere àti igi títóbi , ó sì nawọ gán àwọn igi, ṣùgbọ́n nítorí àwọn igi náà lefo lórí omi, kò wúlò fun.
Atilọlá se àkíyèsí ile, ó sì i kígbe ní ohùn rara, ‘Ẹ gbà mí ooo, Ẹ jọ̀ọ́ , ẹ ràn mí lọwọ,’ ó ń ké sí onílé náà kí ó ran òun lọ́wọ́ ; Ìjàpá ni ó ń gbé inú ilé yìí …
Ó si ferese rẹ , ó rí Atilọlá tí odò ń gbé lọ . Ní kíá ó bo sóde , ó mú igi gígùn kan tí ó wà ní ojúde rẹ, ó sì naa sí Atilọlá . Ọmọ náà gba igi yìí mú dan-in-dan-in bí Ìjàpá tí faa kúrò nínú omi. Bí ọmọkùnrin yíì ti jàjàbó , Ìjàpá mú wo ilé rẹ , ó dá iná fún láti yá, ó sì fun ni oun jíjẹ , ṣùgbọ́n Ìjàpá ologbon ẹwẹ kìí soore fún ni láì sìrègún . Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ronú ohun tí òun le rí gbà lọ́wọ́ ọmọ náà . Ni gẹ́rẹ́ ti ọmọ náà jeun tán , ó mú orin b’enu ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọrin eléyìí tí Ìjàpá kò gbọ́ . Ohun ọmọ náà dùn gbọ́ létí , ó jẹ orin olohun gbòòrò ; orin tí ìyá Atilọlá máa nkọ fun. Orin na lo bayi pe,
ORIN ÀÀLÓ=
àtúnṣe‘Ọmọ o, e ii pẹ̀ da
gbà
Ọmọ o, e ii pẹ dàgbà a
Ọmọ o….
Bi ọmọ náà ti korin tán , ọmọ náà sùn . Ijapa sì ń ronú pé , ‘kíni mo le se?’ Ìjàpá sì lọ síbi tí ọmọ náà sun sí , ó bere si lu ìlù ńlá kan. Nígbà tí o di ọjọ́ kejì tí ọmọ náà ji, Ìjàpá pe é ó ní kí o joko sínú ilu náà . Ọmọ náà dáhùn pé, èé ṣe tí èmi ó fi jókòó sínú ìlù ?’ Ìjàpá ni, pẹ̀lú oore ńláǹlà ti mo se ti mo gbà ọ lọ́wọ́ ikú, se ó yẹ kí o ma a bí mí ní béèrè - kí béèrè. ó yá wọnú ìlù lọ. Mo fẹ́ dán an wò , bí ohùn ìlù náà se jẹ́ ni.
Ọmọ yí wọnú ìlù ó joko, Ìjàpá sì mú awọ ìlù o fi bo ìlù, ó wá sọ fún ọmọ náà pé, bí mo bá ti fi ọwọ gbá ìlù kí o bẹ̀rẹ̀ sí kọrin pé :
‘Omo o, e ii pe dagba..’
ÌJÀPÁ gbe ìlù na, o ta kan, o di ojúde láàrin ọjà.
Ni ìlù yi, ìyá àti baba ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí wá a. Ọkàn wọn pò ruuru, nítorí ọmọ náà kò padà wálé nígbàtí ojo dá. Wọ́n wa títí tí wọn kò ri. Wọn wá rìn lọ ààfin wọn sọ fún ọba pé ọmọ àwọn ti sọnù , wọn kò ri.
Bayi ni oba ran awon onise oba lati wa. Won wa gbogbo afonifoji, won ko ri. Nitorina won pada lo jabo f’oba wipe awon ko ri.
Ijapa ko mo pe won nwa omo yi. Sugbon o bo si aarin oja o ni,
‘Ẹ wá wò ìlù tí ń kọrin , ìlù àràmọ̀ǹdà
‘Ẹ wá wo ìlù ti nkorin, ilu àràmọ̀ǹdà
‘Ẹ wá wo ìlù yi o, àràmọ̀ǹdà ni.
Nígbà tí àwọn èèyàn péjọ, Ìjàpá gbáá ìlù, ọmọ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí kọrin pé :
ORIN ÀÀLÓ
àtúnṣe‘Ọmọ ò , e i pẹ́ dàgbà,
Ọmọ ò, e i pé dàgbà,
Kékeré jòjòló mo gbọmọ mi
Ọmọ ó ẹ í pé dàgbà o
eii pẹ́ dagba,
Báyìí lọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí kọrin lóhùn gooro, ohùn rẹ sì dùn lọpọlọpọ . Àwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí jó , wọn nsọ gèlè àti fìlà wọn silẹ . Wọn jó jó jó títí o fi rẹ̀ wọn, wọn da owó silẹ, wọn sì fún Ìjàpá ní owó goboi nítorí ìlù àràmọ̀ǹdà yìí.
Ní ọjọ́ kejì ọba ránṣẹ́ pe Ìjàpá , ó ní kó wá pẹ̀lú ìlù rẹ sí ààfin òun. Nígbà tí Ìjàpá dé ‘bẹ, enu yàá láti
rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tí wọn jókòó, inú rẹ dùn lọ̀pọ̀lọpọ̀.Ó sọ fún ọba pé òun kò lè lu ìlù láìgbà owó, ó yà ọba lẹ́nu láti gbó èyí, sugbon ó fún Ìjàpá ní àpò kan nítorí ó fẹ́ gbọ́ ìlù tí wọn ń sọ. Báyìí ni Ìjàpá gbá ìlù lórí mọ́lẹ̀ tí ọmọ yìí sí bẹ̀rẹ̀ si níí kọrin,
ọmọ ó, e í pé dàgbà
‘Ọmọ o, e í pé dàgbà ,’
Ó kọrin náà gbogbo ènìyàn bèrè sí ní jọ, ọba àti àwọn ìjòyè rẹ jó jó jó títí ó fi rẹ wọn. Bí ọba tí ń jó, ó ṣàkíyèsí ìyá Atilola tí ó jókòó sí kọ̀rọ̀ tí ó ń sunkún, inú bí ọba, ó ní kí wọn pé bàbá àti ìyá Atilola wá sí iwájú òun, nígbà tí wọ́n dé ọdọ ọba wọn ní ìlù tí Ìjàpá ń lù kìí se ìlù lásán, ọmọ òun ló ń kọrin nínú ìlú náà, kò sì ìyá tí yóò gbọ́ ohùn ọmọ rẹ tí kò níí tẹ etí, ọba pàṣẹ kí gbogbo ìlú jókòó, ọba ní kí wọn fa ìlù náà ya. Ní Atilola bá jáde nínú ìlú, bí ó ti rí àwọn òbí rẹ ni ó sáré fò mọ wọn, ọba ní kí wọn gbé Ìjàpá sí ẹ̀wọ̀n, Ìjàpá ni òun ní ọ̀rọ̀ láti sọ, ó ní òun ni òun gba ọmọ yẹn nígbàtí àgbàrá ojo ń gbé lọ, ọba ronú sì ọ̀rọ̀ tí Ìjàpá sọ yìí, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ikilọ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dán irú rẹ wò mọ, ọba pàṣẹ kí Ìjàpá dá owo ọwọ rẹ padà ní ọgán, Ìjàpá sì gbé owo náà jáde ó dáa padà fún Kabiyesi.
Ẹ̀KỌ́ INÚ ÀÀLÓ
àtúnṣeO ṣe pataki fun àwọn ọmọde lati ma a gboran si awon obi won lenu. Nítorí ẹ̀kọ́ tí Atilólá ti kọ yìí, ó mú ẹ̀kọ́ náà lọ, ó sì di akíkanjú ọkùnrin.