infant tàbí ọmọ jòjòlọ́ jẹ́ ọmọdé tí kò tíì pé ọdún kan. Yorùbá ma ń pè wọ́n ní ọmọ titun tàbí ọmọ jòjòlọ́.

Ìrísí wọn àtúnṣe

Èjìká àti ìbàdí ọmọdé ma ń sábà fẹ̀, ikùn wọn ma ń tóbi díẹ̀.

Orí ọmọdé àtúnṣe

 
Ọmọ oṣù mẹ́jọ; ojú ọmọdé ma ń sábà tóbi nígbà tí a bá fi wé títóbi orí wọn.

Orí ọmọdé ma ń sábà tóbi, òkè orí wọn(ibi tí ọpọlọ wà) sì ma ń tóbi ju ìyókù orí wọn lọ. Orí ọmọ aṣẹ̀ṣẹ̀bí sì ma ń tóbi tó 33–36 cm.[1]

Irun ọmọdé àtúnṣe

 
Irun ọmọ obìnrin ọdún kan

Àwọn ọmọdé kọ̀kan ma ń ní irun tí ó rẹwà lára irun yìí ni wọ́n pè ní lanugo. Ènìyàn le ṣàkíyèsí rẹ̀ ní ẹ̀yìn, èjìká, etí àti ojú àwọn ọmọdé tí kò lò iye ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù tí ó yẹ kí wọ́n lò nínú ìyá wọn. Lanugo ma kúrò larin ose díẹ̀ lẹ́yìn ìbí. Wọ́n le bí ọmọdé pẹ̀lú irun tí ó kún lórí; àwọn míràn, pàápàá jù lọ àwọn ọmọ òyìnbó ma ń ní àwọn irun tí ó tín-ín-rín tàbí kí wọ́n má ní irun rárá.

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. Wallace, Donna K.; Cartwright, Cathy C. (2007). Nursing Care of the Pediatric Neurosurgery Patient. Berlin: Springer. p. 40. ISBN 978-3-540-29703-1. https://books.google.com/books?id=G6o3uSlfRKcC&pg=PA40.