Ipa àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 lórí iṣẹ́ ìròyìn
Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 kọjá ọ̀rọ̀ ẹ̀fẹ̀, ipa tó burú jáì ló ní lórí iṣẹ́ ìròyìn, pàápàá jù lọ àwọn àwọn oníṣẹ́ ìròyìn káàkiri gbogbo àgbáyé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé-ìròyìn abẹ́lé ni Covid-19 ti ṣe àkóbá fún, nípa mímú wọn pàdánù owó ìpolówó-ọjà. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn oníṣẹ́ ìròyìn ló pàdánù iṣẹ́, tí àwọn ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn mìíràn kógbá wọlé.[1][2] Púpọ̀ nínú àwọn ìwé-ìròyìn paywalls ló ṣe àdínkù àwọn ibi tí wọ́n lè ṣe àwárí wá ìròyìn nípa Covid-19 dé.[3][4] Àwọn oníṣẹ́ ìròyìn ti ṣíṣe takuntakun láti ṣe ìròyìn tó pójú owó láti tako àwọn ìròyìn òfegè nípa àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19, àwọn ìròyìn nípa ètò ìlera àti àwọn ìròyìn adárayá láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn lè borí ipa burúkú àrùn náà.[5]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Hsu, Tiffany; Tracy, Marc (23 March 2020). "Local News Outlets Dealt a Crippling Blow by This Biggest of Stories". The New York Times. https://www.nytimes.com/2020/03/23/business/media/coronavirus-local-news.html.
- ↑ "Africa's media hit hard by COVID-19 crisis". Deutsche Welle. 14 May 2020. https://www.dw.com/en/africas-media-hit-hard-by-covid-19-crisis/a-53427253.
- ↑ Jerde, Sara (March 12, 2020). "Major Publishers Take Down Paywalls for Coronavirus Coverage". Adweek. https://www.adweek.com/digital/major-publishers-take-down-paywalls-for-coronavirus-coverage/.
- ↑ Kottke, Jason. "Media Paywalls Dropped for COVID-19 Crisis Coverage". kottke.org. Retrieved 18 April 2020.
- ↑ Natividad, Ivan (6 May 2020). "COVID-19 and the media: The role of journalism in a global pandemic". Berkeley News. https://news.berkeley.edu/2020/05/06/covid-19-and-the-media-the-role-of-journalism-in-a-global-pandemic/. Retrieved 30 May 2020.