Ipa tí àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà ti ọdún 2019-2020 ní sí àwùjọ
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàm̀bá tí ó wáyé látipasẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà ti ọdún 2019-2020 ti nípa rẹpẹtẹ lórí agbèègbè àti bójú ọjọ́ ṣe rí. Ìdínkù nínú àwọn ìrìn àjò ojú òfuurufú[1] ti mú kí àwọn ìdọ̀tí afẹ́fẹ́ dínkù gan-an. Ìsémọ́lé àti àwọn ìlànà mìíràn tí wọ́n ṣàmúlò ní ìlú China ti yorísí ìdínkù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún kábóònù[2] tó ń jáde. Ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ń rí sí ètò ilé-ayé ṣe àlàyé pé ìgbésẹ̀ yìí á fi ẹ̀mí tó ń lọ bìi ẹgbẹ̀rún lọ́na ẹ̀tàdínlọ́gọ́rin pamọ́ láàrin oṣù méjì àti jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àjàkálẹ̀ àrùn náà ti mú ìdíwọ́ bá akitiyan àwọn tó ń rí sí ìpèsè àyíkà tó jọjú, ó sì tún fa ìsúnsíwájú àpéjọ ti United Nations Climate Change fún ọdún 2020[3]. Ìdínkù nínú ètò ọ̀rọ̀-ajé tí ó wáyé látipasẹ̀ ìdálọ́wọ́dúró lágbàáyé ti wà ní àsọtẹ́lẹ̀ pé yóò fa súnkẹrẹfà nínú ìdókòwò ti àwọn ilé-iṣé tí ń pèsè agbára.
Ìpìlẹ̀
àtúnṣeTítí di ọdún 2020, pípọ̀si àwọn èéfín tó ń jáde ní ilé-iṣé greenhouse ti yọrí sí ìdìde nínú ìwọ̀n òtútù lágbàáyé[4]. Èyí sì nípa lóríṣiríṣi tí ó tún fa yíyọ́ áísìì. Ìṣe àwọn èèyàn náà fa ìbàjẹ̀ àyíká lóríṣiríṣi. Ṣáájú àjàkálẹ̀ àrùn náà, àwọn ìgbésẹ̀ tí ó wà nílẹ̀ tí a sì ní làti fí lọ àwọn elétò ìlera bí a bá ní ìṣòro àjàkálẹ̀ àrùn ni ìséraẹnimọ́lé àti jíjìnà síra ẹni. Àríyànjiyàn ta láàrin àwọn olùṣèwádìí látàri pé bí ètò ọrọ̀-ajé bá lọlẹ̀ díẹ̀, àbájáde rè yóò fa ìdínkù nínú global warming, ìdọ̀tí afẹ́fẹ́ àti omi tí á sì mú kí agbègbè wà lálàáfíà.
Ìdọ̀tí afẹ́fẹ́
àtúnṣeLátàri ipa tí ìtànkálẹ̀ àrùn kòrónà ní lórí ìrìn àjò àti ilé-iṣẹ́, ìdọ̀tí afẹ́fẹ́ ti dínkù ní àwọn agbègbè kan. Ìdínkù nínú ìdọ̀tí afẹ́fẹ́ le mú ìdínkù bá climate change àti àwọn ewu tó wà nínú ìtànkálẹ̀ àrùn náà[5]. Àmọ́ kò ì sí ìdánilójú irúfẹ́ ìdọ̀tí afẹ́fẹ́ tó wọ́pọ̀ sí ewu inú climate change àti covid-19. Àjọ tó ń rí sí ṣíṣe ìwádìí lórí ìpèsè iná àti ìmọ́tótó afẹ́fẹ́ ti sọ ọ́ di mímọ̀ pé àwọn ọ̀nà láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn náà b́ii ìséraẹnimọ́lé àti ìdíwọ́ nínú ìrìn àjò ti yọrí sí ìdínkù ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún èéfín kábọ́ọ̀nù tí ìlú China ń gbé jáde. Ní oṣù àkọ́kọ́ tí gbogbo ilé wà ní títì pa, ìlú China ṣe àgbéjáde ìdiwọ̀n tó tó igba mílíọ́ọ̀nù ton kábọ́ọ̀nù ju èyí tí wọ́n gbé jáde ní ọdún 2019 látipasẹ̀ ìdínkù nínú súnkẹrẹfà ojú òfuurufú, àtúnṣe epo rọ̀bì àti èédú. Ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ń rí sí ètò ilé-ayé ṣàlàyé pé ìdínkù yìí á gba ẹ̀mí àwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀tàdínlọ́gọ́rin là. Síbẹ̀síbẹ̀, Sarah Ladislaw láti àjọ Strategic and international studies ṣe àríyànjiyàn pé a ò gbọdọ̀ rí ìdínkù nínú àwọn èéfín yìí gẹ́gẹ́ bí àǹfààní nítorí ìgbìyànjú ìlú China láti mú kí ìdàgbàsókè dé bá ètò ọrọ̀-ajé àti ìṣòwò wọn le yorí sí ìjàm̀bá tó máa le ju tàtèyìnwá lọ.[6] Láàrin ọjọ́ kìínì oṣù kìíní sí ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹta ọdún 2020, European Space Agency ṣàkíyèsi pé ìdínkù dé bá èéfín nitrous oxide láti ara ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, àwọn ẹ̀rọ amúnáwá àti ilé-iṣé ní agbègbè Po Valley ní apá àríwá Italy. Ìdínkù yìí wáyé lákòókò tí gbogbo ilé àti ilé-iṣẹ́ wà ní títì pa lágbègbè náà. NASA àti ESA ti ń ṣàmójútó ìdínkù àwọn èéfín wònyí lákòókò tí àjàkálẹ̀ àrùn náà kọ́kọ́ wáyé ní ìlú China. Súnkẹrẹfà nínú ètò ọrọ̀-ajé látàri àjàkálẹ̀ àrùn náà fa ìdínkù nínú ìdọ́tí ní àwọn agbègbè kan pàápàá ní Wuhan ní ìlú China. Ìdínkùn náà wọ ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún[7]. NASA lo irinṣẹ́ kan tí a mọ̀ sí Ozone monitoring instrument (OMI) láti ṣàtúnpalẹ̀ àti láti ṣàkíyèsí ozone layer àti àwọn ìdọ̀tí tó ń ba agbègbè jẹ́ bíi NO2, aerosols àti àwọn mìíràn. Irinṣẹ́ yìí ran NASA lọ́wọ́ láti ṣàmójútó àti láti ṣètunmọ̀ àwọn èsì tó ń wọlé látàri ìtìpa lágbàáyé.[8]
Àwọn ọ̀nà omi àti àwọn nǹkàn ẹlẹ́mìí inú omi
àtúnṣeLátàri àjàkálẹ̀ àrùn náà, ìdínkù ti dé bá ẹja títà àti iye tọ́ ń tà á[19], èyí sì mu kí àwọn ẹja inú omi ó máa ṣègbádùn ara wọn. Rainer Froese ti sọ ọ́ di mímọ̀ pé àwọn ẹja inú omi yóò tóbi si nítorí ìdínkù ti dé bá ẹja pípa. Ó sì ṣàlàyé pé nínú omi Europe, àwọn ẹja bíi herring le di ìlọ́po méjì nínú òṣùwọ̀n.[9]
Ìwádìí àti ìdàgbàsókè
àtúnṣeBí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdínkù fún ìgbà díẹ̀ wáyé ní ti èéfín kábọ́ọ̀nù káàkiri àgbáyé, International Energy Agency ṣe ìkìlọ̀ pé wàhálà tó dé bá ètò ọrọ̀-ajé látàri àjàkálẹ̀ àrùn náà le fa ìdíwọ́ tàbí ìdádúró àwọn ilé-iṣé tó fẹ́ dókòwò pẹ̀lú àwọn ilé-iṣé green energy. Síbẹ̀síbẹ̀, àfàgùn àkókò ìyàsọ́tọ̀ ti mú kí àwọn iṣẹ́ ọ̀nà jíjìn gbòrò si. Gẹ́gẹ́ bí àbájádè àìmọ̀ tẹ́lẹ̀, àwọn aṣọ ìbòjú tí àwọn èèyàn ń sọ sílẹ̀ káàkiri ń dákún ìṣòro ìdọ̀tí àyíká. European Centre for Medium-Range Weather Forecasts (ECMWF) ṣe ìkéde pé ìdínkù tí ó dé bá ìrìn àjò ojú òfuurufú le mú kí àwọn àfojúsùn ojú ọjọ́ tọ̀nà. Èyí sì wáyé nítorí ìlò Aircraft Meteorological Data Relay (AMDAR) fún ìṣòwò, èyí sì jé irinṣẹ́ kan tó gbòógì láti ri pé àwọn àfojúsùn ojú ọjọ́ tọ̀nà. Àjọ ECMWF ṣe àsọtẹ́lẹ̀ pé èsì àwọn AMDAR máa díkù pẹ́lù ìdá márùn-úndínláàádọ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ látàrí ìdínkùn tí ó dé bá lílo ọkọ̀ òfuurufú.
Òṣèlú
àtúnṣeÀjàkálẹ̀ àrùn náà ti fa ìsúnsíwájú àpéjọ ti 2020 United Nations Climate Change Conference lẹ́yìn tí wọ́n sọ ibi tí àpéjọ náà á ti wáyé di ilé-ìwòsàn. Àpéjọ yìí ṣe pàtàkì gan-an nítorí àjọ àgbáyé ti ṣètò láti gba àbá orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ fún Paris Agreement. Àjàkálẹ̀ àrùn náà mú ìdíwọ́ bá fífi èrò orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan hàn nítorí ọ̀rọ̀ àrùn náà ni gbogbo orílẹ̀-èdè ń gbọ́. Ìwé ìròyìn Times magazine sọ ọ́ di mímọ̀ pé èrò láti tún ètò ọrọ̀-ajé lágbàáyé bẹ̀rẹ̀ tún le fa àfikún àwọn èéfìn kábọ́ọ̀nù. Àmọ́ olùdarí fún International Energy Agency ṣàlàyé pé ìdínkù nínú iye owó epo ròbí lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn náà le jẹ́ àǹfààní ńlá láti dẹ́kun ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ epo ròbì.
Ipa àtúnṣe àwọn àsọtẹ́lẹ̀
àtúnṣeÀtúnbẹ̀rẹ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ tó ń pèsè gáàsì àti àwọn ọkọ̀ ìrìnà ni a rí gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa mú kí ìpèsè gáàsì pọ̀ si.
Awon Itokasi
àtúnṣe- ↑ Team, The Visual and Data Journalism (28 March 2020). "Coronavirus: A visual guide to the pandemic". BBC News. Archived from the original on 27 March 2020.
- ↑ Myllyvirta, Lauri (19 February 2020). "Analysis: Coronavirus has temporarily reduced China's CO2 emissions by a quarter". CarbonBrief. Archived from the original on 4 March 2020. Retrieved 16 March 2020.
- ↑ "Cop26 climate talks postponed to 2021 amid coronavirus pandemic". Climate Home News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 1 April 2020. Archived from the original on 4 April 2020. Retrieved 2 April 2020.
- ↑ McMahon, Jeff (16 March 2020). "Study: Coronavirus Lockdown Likely Saved 77,000 Lives In China Just By Reducing Pollution". Forbes. Archived from the original on 17 March 2020. Retrieved 16 March 2020.
- ↑ Burke, Marshall. "COVID-19 reduces economic activity, which reduces pollution, which saves lives.". Global Food, Environment and Economic Dynamics (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 16 May 2020.
- ↑ "Europe's moment: Repair and prepare for the next generation". European Commission - European Commission (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 4 June 2020.
- ↑ Zhang, Ruixiong; Zhang, Yuzhong; Lin, Haipeng; Feng, Xu; Fu, Tzung-May; Wang, Yuhang (April 2020). "NOx Emission Reduction and Recovery during COVID-19 in East China" (in en). Atmosphere 11 (4): 433. doi:10.3390/atmos11040433. https://www.mdpi.com/2073-4433/11/4/433. Retrieved 6 May 2020.
- ↑ "5 things to know about the EU green recovery". POLITICO (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 4 June 2020.
- ↑ McMahon, Jeff (16 March 2020). "Study: Coronavirus Lockdown Likely Saved 77,000 Lives In China Just By Reducing Pollution". Forbes. Archived from the original on 17 March 2020. Retrieved 16 March 2020.