Ipese Drum

ÌPÈSÈ:-

Ìlù tí àwọn babaláwo ńlù lọjọ ọdún ifá ni Ìpèsè. Awọn mìíran npe e ni Ìpẹ̀sì. Yatọ̀ si ọjọ ọdun ifa, a tun nlù Ipese lọjọ̀ ti a ba n ṣe isinku tabi ijade oku ọkan nínú àwọn asaaju nibi Ifa. Mẹrin ni ọ̀wọ́ ìlù ti a papọ se Ìpèsè:-

(a) Ìpèsè:- Ìlù yi funra rẹ lo tóbi jù nínú mẹ́rèẹ̣́rin. Igi la fi n gbẹ ẹ. Ó sì gbà tó ẹsẹ bata ti a fi bo o loju mọ ara igi ti a gbẹ ti a si da ìho sinu rẹ.

(b) Àféré:- Ìlù yìí lo tobi tẹle Ipese. Igi la fi n gbẹ àféré, ṣùgbọ́n o lẹgbẹ ti o fẹ jù ipese ko ga to ipese, ẹsẹ mẹta ni o fi dúró nilẹ.

(d) Àràn: Ìlù yìí kò tobi to Aféré, bẹẹ ni ko ga to o. Òun náà ni ẹsẹ̀ mẹ́ta to fi dúró

(e) Agogo:- Ohun kẹ́rin ti a n lù si Ìpese ni agogo. Irin la fi ńrọ agogo. Abala ìrìn meji ti a papọ, ṣùgbọ́n ti a da ẹnu rẹ si lapa kan ni agogo.