Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom
Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní agbègbè ẹkù-ìjọba Gúúsù-Gúúsù orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó pín ààlà ní ìlà-oòrùn pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Cross River State, ní ìwọ̀-oòrùnon ìpínlẹ̀ Rivers àti Ìpínlẹ̀ Abia, àti ní gúúsù pẹ̀lú Òkun Atlantic. Ìpínlẹ̀ náà mú orúkọ rẹ̀ látara orúkọ odò Qua Iboe tí ó pín Ìpínlẹ̀ náà sí ọgbọọgba kí ó tó sàn wọ inú Bight ti Bonny.[1] Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom yapa wá látara Ìpínlẹ̀ Cross River nínú ọdún 1987 pẹ̀lú olú-ìlú rẹ̀ Uyo pẹ̀lú àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kànlélọ́gbọ̀n.
Láàárín àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìpínlẹ̀ Akwa Ibom jẹ́ ìpínlẹ̀ ọgbọ̀n tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè àti ẹlẹ́ẹ̀karùndínlógún ní iye pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù márùn-ún-àbọ̀ gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún 2016.[2]
Ayé òde-òní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ti ní olùgbé láti bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn tí ó kúnfún àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́ àbátan Ibibio, Anaang, àti Obolo - Oron àwọn ènìyàn ní àríwá-ìlà-oòrùn, àríwá-ìwọ̀-oòrùn, àti agbègbè gúúsù Ìpínlẹ̀ náà, lẹ́sẹsẹ. Ní àkókò ìmúnisìn, Ohun tí a wá mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀ Akwa Ibom báyìí pín sí oríṣiríṣi ìlú-ìpínlẹ̀ bíi Ibom Kingdom àti Akwa Akpa kí ó tó padà di Ìpínlẹ̀ lẹ́bẹ́ àbò ìjọba aláwọ̀-funfun ní 1884 gẹ́gẹ́ bí apákan Oil Rivers Protectorate.[3]
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi
àtúnṣe- ↑ Onyeakagbu, Adaobi (5 October 2021). "See how all the 36 Nigerian states got their names". Pulse.ng. Retrieved 22 December 2021.
- ↑ "Population 2006-2016". National Bureau of Statistics. Retrieved 14 December 2021.
- ↑ Àdàkọ:Cite EB1911