Parkia filicoidea00.jpg

Irú
Iru

Irú (locust beans) jẹ́ ọ̀kan nínú ìsebẹ̀ amọ́bẹ̀dùn. Iru jẹ èròjà ọbẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá àti káàkiri ibi tí wọ́n ti mọ ìwúlò rẹ̀. A máa ń fi irú sí ọbẹ̀ láti fi jẹ́ kí ó ní adùn àti òórùn dáadáa. Awọn ọbẹ ti a le fi irú si ni ọbẹ ila, ọbẹ ewedu, ọbẹ ẹfọ, ọbẹ ata, ọbẹ egusi, ọbẹ ọgbọnọ ati bẹẹ bẹẹ lọ. Irú ni ilẹ Yoruba pin si oriṣi meji, irú woro ati iru pẹtẹ. Iyaatọ laarin mejeeji ko pọ. Irú pẹtẹ rọ, o si maa nfọ sinu ọbẹ. Sugbọn irú woro maa nduro sinu ọbẹ nitori pe ole. Irú jẹ eronja ọbẹ to ṣara lore.[1] Awọn ọmọ ilẹ Yoruba ni igbagbọ pe irú ni anfaani ti on ṣe fun oju lọpọlọpọ. Nitori eyi, wa maa sọ fun ẹni ti oju dun ki o ma jẹ iru daadaa. Akiyesi irú ni pe o gbọdọ kun fun iyọ ki o ba le pẹ nilẹ. [2]

Awọn Itọkasi

àtúnṣe
  1. Odumade, Omotolani (2018-04-13). "Health benefits of Iru". Pulse.ng. Retrieved 2018-10-15. 
  2. Abaelu, Adela M.; Olukoya, Daniel K.; Okochi, Veronica I.; Akinrimisi, Ezekiel O. (1990). "Biochemical changes in fermented melon (egusi) seeds (Citrullis vulgaris)". Journal of Industrial Microbiology 6 (3): 211–214. doi:10.1007/BF01577698.